Lagos doctors strike: Ẹgbẹ́ dókítà bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì lórí owó oṣù àti ètò adójútòfò fún ìtọ́jú covid-19

Gomina Babajide Sanwo-Olu atawọn eleto ilera to n tọju covid-19

Oríṣun àwòrán, Twitter/Prof Akin Abayomi

Nibi a ti n ṣe laa tii jẹ. Eyi lo mu ki awọn dokita to n ṣiṣẹ lawọn ile iwosan ipinlẹ Eko gunle iyanṣẹlodi ọlọjọ mẹta lati ṣe ikilọ fun ijọba.

Awọn dokita labẹ asia ẹgbẹ awọn dokita onisẹgun nipinlẹ Eko, Medical Guild Association sọ pe ijọba n jẹ awọn ni owo oṣu meji.

Bakan naa lawọn dokita n ja fun aabo to peye lẹnu iṣẹ ati eto adojutofo fun wọn.

Ipinlẹ Eko ni aarun coronavirus ti pọ ju lorilẹede Naijiria, eeyan to le lẹgbẹrun mejila lo laarun naa nipinlẹ nikan ninu ẹgbẹrun mejilelọgbọn eeyan to ni covid-19 ni Naijiria.

Alaga awọn dokita naa, to ba BBC sọrọ, Dokita Oluwajimi Sodipo ṣalaye pe ọrọ aabo fawọn dokita to n tọju awọn alaarun covid-19, atawọn ajẹmọnu kan to fi mọ iyatọ to wa laarin awọn dokita to n ṣiṣẹ lawọn ile iwosan ijọba apapọ lawọn fẹ ki ijọba ipinlẹ Eko nkan ṣe si i.

Ọgbẹni Sodipo sọ pe ninu ewu nla ni awọn dokita tọju awọn to laarun coronavirus wa, notori naa, o yẹ ki ijọba wa nkan ṣe si ọrọ aabo wọn lẹnu iṣẹ.

''Awọn dokita fẹ ki ijọba pese aṣọ idaabobo to peye, eto adojutofo ati eto lati maa ṣe ayẹwo deedee fawọn dokita atawọn oṣiṣẹ eleto ilera,'' Dokita Sodipo lo woye bẹẹ.

Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Eko ti sọ pe oun yoo ṣepade pẹlu awọn dokita naa lati wa ojutu si ọrọ wọn.

Ẹru n ba ọpọ eeyan nipinlẹ Eko pe o ṣeeṣe ki iyanṣẹlodi awọn dokita ko pẹ eyi ti yoo ṣakoba fun akitiyan ijọba lati dẹkun itankalẹ coronavirus l'Eko.

Àkọlé fídíò, Ọmọ ọdún méjìlá yìí sọ bó ṣe di téélọ̀ táwọn àgbà ń bẹ́rí fún