Nigeria Police recruitment 2020: Ṣé àbáwọle sójú òpó NPF policerecruitment.gov.ng.ng yìí níra? wo àwọn nọ́mba ọlọ́pàá tí o lé pé láti mọ ọ̀nà àbáyọ

Oríṣun àwòrán, Others
Bí ètò ìfórúkọsíll fún ìgbànísíṣẹ̀ ọlọ́pàá kò ṣe ku bí oṣù kan ti yóò kágbá nílẹ̀, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fí ìpè síta lórí ayélujára wọ́n.
Èyí ni láti ran àwọn ti o ni ẹ̀hónú kan tàbi òmíràn láti sọ lórí ìdàmú ti wọ́n ń kojú láti fi orúkọ silẹ̀ fún iṣẹ́ ọlọ́pàá.
- Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbaníwọlé- Àwọ ìlànà ìforúkọsilẹ̀ rèé
- Bí o ṣe lè forúkọ silẹ̀ fún ètò "N75BN Nigerian Youth Investment Fund" rèé...
- Ò kéré tán N1million là ń ná lórí alárùn Coronavirus kọ̀ọ̀kan; àlàyé rèé- Ìjọba Eko
- Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Nàìjíríà dóòlà ẹ̀mí ẹni méjì ní Owena ní Ondo
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá lórí àtẹ̀jíṣẹ́ twitter wọ́n ti sàlàyé pé irú àwọn ènìyàn báyìí lé pé nọmba yìí ) 081 0004507 tàbí kí wọ́n fi àtẹ̀jíṣẹ́ ránṣẹ́ sí:
email to [email protected] tàbí [email protected]
Ojú òpó ti ó ti lè fórúkọ sílẹ̀ fún ìgbànisíṣẹ̀ ọlọ́pàá sí wa ní ṣíṣí títí di àsìkò yìí àti pé ọmọ Naijiria to bá sì nífẹ̀ sii le forúkọ fun ètò ìgbànisíṣẹ́ ọlọ́pàá ọdun 2020.
Ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù keje, ọdún 2020 ni ojú òpó ìgbànisíṣẹ́ náà sí sílẹ̀ tí yóò sì pari ni ọjọ́ kẹtàlélógún, oṣù kẹjọ, ọdún 2020.

Oríṣun àwòrán, NPF
Oriṣiriṣi ibeere lo n waye lori eto igbani sisẹ ileesẹ ọlọpaa Naijiria fún ọdun 2020 eyi to n waye lọwọ lọwọ.
Fi orukọ silẹ ni oju opo igbanisiṣẹ ọlọpaa
Eyi lo mu ki a ṣe akojọpọ idahun ranpẹ si awọn ibeere náà.
Ṣe eto igbani sisẹ ti bẹrẹ?
Idahun: Bẹẹni, ó ti bẹrẹ. Ọjọ Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ni ijọba ti ṣi oju opo itakun agbaye fun eto igbani sisẹ naa.
Awọn eeyan ti ọjọ ori wọn wà laarin ọdun mẹtadinlogun mẹẹdọgbọn, ni eto naa wa fun.
Ileesẹ ọlọpaa sọ pe ọsẹ mẹfa ni iforúkọ silẹ fun eto igbani sisẹ naa yoo fi waye, laarin ọjọ kẹrinla, oṣu Keje, si ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹjọ.
Ọ̀fẹ́ si ni iforukọsilẹ fun eto naa.
- Iléeṣẹ́ Ọlọ́pàá ṣetán láti bẹ̀rẹ̀ ètò ìgbanisíṣẹ́ lákọ̀tun
- Wọ́n ti yìnbọn pa olórí ẹgbẹ́ jàndùkú ''One Million Boys'' ní Ibadan’
- Ìwà Jẹgúdújẹrá ní Naijiria kò gba òjú bọ̀ọ̀rọ̀ - Aarẹ Buhari
- Wo àwọn nkan tí ó yẹ kí o mọ̀ nípa Bitcoin, kí o tó ó dáwọ́ le e
- Olorì àgbà mẹ́rin tó jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún Aláàfin Adeyemi
Bawo ni mo ṣe lee darapọ mọ ileesẹ ọlọpaa Naijiria?
Idahun:
- Nkan akọkọ ti o nilo lati ṣe ni pe ki o lọ si itakun agbaye ileesẹ ọlọpaa, www.policerecruitment.gov.ng, lori ayelujara.
- Fi sọkan pe, ẹnikẹni to ba fẹ ẹ fi orukọ silẹ fun iṣẹ yìí, gbọdọ jẹ ọmọ orilẹ-ede Naijiria. O si gbọdọ ni nọ́mbà idanimọ gbogboogbo, National Identity Number (NIN).
- Ko tán sibẹ o. O gbọdọ ni kirẹẹditi márùn-ún ninu eyikeyi idanwo WASSCE/GCE/NECO/NABTEB, ti o ṣe lai ju ẹẹmeji lọ. Dandan si ni kirẹẹditi ninu imọ ìṣirò ati èdè Gẹẹsi.
- Eto ilera ara rẹ gbọdọ peye.
- Anfaani ko si fun obinrin to ba wa ninu oyun lati forúkọ silẹ.
- Lori itakun agbaye naa ni wa ti ri awọn idahun miran to kan ọrọ ọkùnrin ati obinrin.
Oya, wo ilana ti wa tẹle lẹsẹẹsẹ fun igbani sisẹ ọdun 2020
- O gbọdọ ni imeeli to n sisẹ, ati nọ́mbà NIN, ki o to bẹrẹ iforukọsilẹ.
- Oju opo yii > https://bit.ly/2Zim6Ua, ni wa a tẹle nibẹ lati seto iforukọsilẹ rẹ.
- Bakan naa ni ki o ri i daju pe o tẹ ẹ̀dà (print) ohunkóhun ti kọmputa ba fi ránṣẹ si imeeli rẹ, nigba ti o ba fi orukọ silẹ tan.
- Ri i daju pe o kọ nọ́mbà iforukọsilẹ rẹ pamọ nitori ọjọ iwájú.
- Ti o ba yege bọ si ipele keji eto igbani sisẹ naa, o o nilo lati tẹ (print) imeeli ti wọn fi ránṣẹ si ọ pe o ti bọ si ipele keji.
Elo ni owo oṣu ọlọpaa ni Naijiria?
Idahun:
Eyi ni alakalẹ diẹ lara ilana owo oṣu ọlọpaa ni Naijiria:
1. Police Recruit - N108, 233
2a. Police Constable Grade Level 03 - N519, 525.60
2b. Police Constable Grade Level 10 - N613, 363.08
3a. Police Corporal Level 04 (1) - N536,586.36
Ti o ba yege ninu eto iforukọsilẹ lori ayelujara, ileesẹ ọlọpaa yoo ránṣẹ pe ọ lati farahan fun ayẹwo ojukoroju ti yoo waye ni awọn ileesẹ ọlọpaa kaakiri Naijiria, laarin ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, si ọgbọnjọ, oṣu Kẹjọ, ọdun 2020.
Bakan naa ni wọn yóò fi orukọ awọn to ba yege sinu àwọn iwe iroyin lorilẹ-ede Naijiria.













