Bitcoin: Wo àwọn nkan tí ó yẹ kí o mọ̀ nípa Bitcoin, kí o tó ó dáwọ́ le e

Bitcoin

Oríṣun àwòrán, Reuters

Owó Bitcoin ati awọn owó orí ayelujara miran jẹ owó airi. O si le lo wọn lati ra ọja tabi sanwo fun iṣẹ ti ẹnikan ṣe fun ọ - fun àpẹẹrẹ, o le fi Bitcoin seto irinajo igbafẹ lori ayelujara.

Awọn owó ori ayelujara to tun wa ni Ethereum, ati Litecoin.

Amuyẹ meji ni Bitcoin ni: owo ori ayelujara ni, awọn kan si tun n ri gẹgẹ bi ọna abayọ miran.

Ko dabi owó beba, tabi owó ẹyọ ti a le ko si àpò tabi apamọwọ, orí ayelujara lo n gbe.

Ikeji ni pe, ijọba tabi awọn banki kọ lo n tẹ owó Bitcoin.

Eyi tumọ si pe 'kii ṣe owó ti ofin faaye gba', o ko si le lo o lati san gbèsè.

Ilana alagbara kan ti wọn n pe ni 'mining', ni wọn n gba ṣẹ̀dá Bitcoin, ọpọlọpọ kọ̀mpútà to já ara wọn ni wọn si fi ń ṣe amojuto ati ìdarí rẹ jakejado agbaye.

Kii din ni 3,600 owó Bitcoin tuntun to n jade lojumọ.

Ṣugbọn sa, itẹwọgba àti ìdíyelé rẹ da lori iye ti awọn eeyan ba pinnu lati rà tàbí tà á.

Ọna wo ni awọn eeyan n gba ra Bitcoin?

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún oriṣiriṣi owó crypto-currency lo ti wa bayii, sugbọn Bitcoin ṣi lo gbajúmọ julọ laarin wọn.

Ẹnikẹni to ba fẹ ẹ gba owó Bitcoin gbọdọ kọkọ ni adirẹsi Bitcoin - eyi ni asopọ nọ́mbà ati lẹta mẹtadinlọgbọn si mẹrinlelọgbọn.

Awọn nọmba ati lẹta naa ni yoo duro gẹgẹ bii 'apoti ifiweransẹ' ori ayelujara, ti Bitcoin yoo ma a wọle si.

Ko si akọsilẹ to so ojulowo orúkọ ati adirẹsi pọ. Eyi si ma n ran awọn olookowo Bitcoin kan lọwọ lati fi ara pamọ.

Àpò àsùnwọ̀n Bitcoin ma n ṣe akọsilẹ awọn adirẹsi naa, o si n lo o lati mojuto eto fifi owó pamọ.

Amojuto Bitcoin fi ara jọ ti àpò àsùnwọ̀n ni banki, pẹlu ilana pe ti awọn akọsilẹ nipa rẹ ba sọnù, owó Bitcoin rẹ naa wọ igbo nìyẹn.

Lara awọn ilana to de Bitcoin ni pe miliọnu mọkanlelogun Bitcoin ni wọn le ṣẹ̀dá - o si ti fẹ ẹ pé bayii. Àmọ́, nkan ti yoo sẹlẹ si ìdíyelé Bitcoin to ba ti pé ko ti i di mimọ dáadáa.

Ṣe wọn le fi Bitcoin ra nkan?

Bi ko ṣe si ọna lati da awọn oludokowo owó orí ayelujara mọ, lo fa ọpọlọpọ eeyan to fẹ ẹ ra àwọn nkan ti ko ba ofin mu lori ayelujara, mọ́ra.

Àmọ́ o, àwọn ilé itaja kan to ba ofin mu ti n faaye gba àwọn onibaara wọn lati fi owó Bitcoin ra ọja, tabi san owó fún iṣẹ́.

Awọn ileesẹ bii ileesẹ ẹrọ ayarabiasa Microsoft, ileesẹ abaniseto irinajo Expedia, ati awọn ileesẹ kéékèèké kan bi ile itaja oúnjẹ lo ti n gba owó Bitcoin.

Iyalẹnu to tun wa lori ọrọ owó yii ni pe, ọpọ àwọn to n lo o kii fi ra nkan.

Onimọ nipa eto ọrọ aje, Dokita Garrick Hileman sọ pe ìdá ọgọ́rin si àádọ́rùn-ún àwọn eeyan naa lo kan fi n dokowo.

Ìhà wo ni àwọn aláṣẹ kọ si?

Amofin kan ni UK, Bradley Rice, sọ pe lọwọ lọwọ, ko si ofin tabi ilana to de okoowo Bitcoin.

Kii si ṣe ojú opo ayelujara to han si gbangba ni wọn ti n ṣe e. Ọ̀nà alùmọkọ́rọ́yí ni wọn n gbe e gba.

Ọrọ owó yii n kọ awọn orilẹ-ede bi i China ati South Korea lomiinu, debi i pe wọn ti fofin de idasilẹ owó tuntun lórí ayelujara.

Sugbọn sa, bi àwọn onimọ kan ṣe sọ pe eto okoowo Bitcoin, ni 'ayẹta', ni awọn miran gba ẹnikẹni to ba fẹ ẹ dokowo Bitcoin láti má fi gbogbo owó to ni sinu rẹ.

Ọgbẹ́ni Rice sọ pe ìdí si niyii ti awọn alamojuto eto owó nina nilẹ Europe ṣe n lo ilana 'ka wo ibi ti yoo ja si'.

Okoowo Bitcoin ni Naijiria

Lati bi ọdun diẹ sẹyin ni Bitcoin ti di gbajúmọ laarin awọn ọmọ Naijiria kan.

Bi awọn kan ṣe n kowo le e, ni ọpọ gbagbọ pe ko yatọ si awọn okowo sogun-dogoji bi i MMM, ti ọpọ eeyan padanu owó si nigba to forisanpọn.

Ori ayelujara bi i Facebook, WhatsApp, Twitter, Instagram, ati bẹẹ bẹẹ lọ si ni wọn ti ma n fa oju awọn eeyan mọ́ra lati dokowo Bitcoin.

Ọpọ eeyan ti ko si ni òye kíkún nípa rẹ ti bọ sọwọ gbajuẹ.

Koda, banki apapọ Naijiria, ati ajọ to n dáabo bo awọn oludokowo ni Naijiria ti kilọ fun awọn ọmọ Naijiria, lati sọra ṣe fún awọn okoowo ti èrè ibẹ ba farajọ majiiki.

Okowo Bitcoin kii fun ni ni èlé bi ìpín idokowo ni banki tabi ileesẹ. Bi idiyele Bitcoin ba ṣe ri ni yoo sọ boya ẹni to fẹ ẹ ta yoo jere.

Fun awọn oludokowo Bitcoin ni Naijiria, owó Dọla nikan ni wọn le fi ṣe e.

Sugbọn ọpọlọpọ banki lo maa n gbẹsẹ le obitibiti owo to mu ifura dani, ti wọn ba ri i pe o ti pẹ ninu àsùnwọ̀n onibaara kan.

Banki apapọ fun wọn ni agbara lati ri iru owo bẹ ẹ bi eyi ti ẹni naa ko jọ latara jibiti, nitori o fẹ ṣi oju awọn eeyan kuro lara okowo Bitcoin.

Ohun to ṣe koko ni pe, ẹnikẹ́ni to ba fẹ ẹ dokowo Bitcoin gbọdọ ni òye kíkún nipa rẹ, ko si ni ikiyesara.