Police Brutality: Bí ọlọ́pàá ṣe bọ́ aṣọ mi tí wọ́n lù mi, wọ́n tún gba #260, 000 lọ́wọ́ mi- Olumide

Àkọlé fídíò, Police Brutality: Bí ọlọ́pàá ṣe bọ́ aṣọ mi tí wọ́n lù mi, wọ́n tún gba #260, 000 lọ́wọ́ mi
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lẹ́yìn ti ọmọkùnrin kan ké gbàjarè lórí àtéjíṣẹ́ twitter lówùrọ ọjọ Iṣẹ́gun ní ọ̀pọ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí ni bẹnu àtẹ́ lu ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Bakare Olumide sàlàyé fún BBC News Yoruba pé, lọ́sàn ọjọ́ ìṣẹ́gun ni àwọn ọlọ́pàá mú ọkọ̀ Uber ti ó gbé àwọn ti wọ́n sì darí àwọn láti lọ si àgọ́ ọlọ́pàá tó wà ni Ogudu l'Eko.

O ní ní kété ti àwọn dé àgọ́ ọlọ́pàá náà ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ si ni tú inú fóònù òun àti ti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ náà tó wà nínú mótò, wọ́n fi àwọn to kù silẹ̀, ṣùgbọ́n wọ́n ṣe alábàpàde ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan lórí fóònù òun ti òun kọ pé "Gay men dey pay" iyẹn ni pe awọn ọkunrin to maa n ba ara wọn lopọ n pawo wọle gidi gan.

Nítorí ǹkan ẹyọkan tí wọ́n rí yìí ni wọ́n fi lọ́ ẹ̀ṣùn m ọ lẹsẹ pé onibalopọ akọsakọ, "Gay" ní òun àti pé òun ni àwọn ọ̀rẹ́kùnrin tí àwọn jọ ń ṣe ìwà ìbàjẹ́.

Ó ní gbogbo ìgbìyanjú òun láti ṣàlàyé fún wọn pé kò rí bẹ́ẹ̀, wọ́n ni kí òun bọ́ asọ wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ni na òun.

Bí ọlọ́páá ṣe bọ́ Aṣọ mi ti wọ́n sì lù mi, wọ́n tú

Oríṣun àwòrán, other

"Wọ́n ní kí n bọ́ aṣọ mi wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ni fi 'Pipe' lù mí" Lásìkò tí wọ́n ń tú fóònù mi wọ́n ri owó ti mo ni, wọ́n sì ní àwọn yóò gba mílíọ̀nu kan Náírà lọ́wọ́ mí'.

"Mo sọ fún wọ́n pé mi ò lé fún wọ́n ni iye owó náà, wọ́n gbé wá silẹ̀ si ìdajì mílíọnu Naira, mó ni mí olè sán-án, wọ́n padà ni kí ń san ẹgbẹ̀run ogójì náírà dín ni ọ̀dúnrun owó.

Lẹ́yìn ti wọ́n fi Olumide kalẹ̀ ní àgọ́ ọlọ́pàá ni ó bẹ̀rẹ̀ si ni kọ irírí rẹ̀ sórí twitter.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bí ọlọ́páá ṣe bọ́ Aṣọ mi ti wọ́n sì lù mi, wọ́n tún gba #260, 000 lọ́wọ́ mi- Olumide

Oríṣun àwòrán, other

"Lẹ́yìn èyí ni àwọn ọlọ́pàá ṣe fídíò míì ti wọ́n sì gbé ìbọn si mi léti pé tí mo bá kọ̀ láti sọ ǹkan ti àwọn bá ṣọ àwon lé pa mi tàbi fi mi sí ẹ̀wọ̀n."

Olumide ni àwọn ọlọ́pàá ni kí òun máa parọ́ mọ́ ara òun pé 'Gay' ni òun kí òun sì máa dárúkọ́ àwọn ènìyàn síi tí oun bá ṣe e sí.

Ọ̀dọ́mọkùnrin náà ni òun kò ṣetan láti ṣe ẹjọ́ ṣùgbọ́n òun rọ gbogbo àwọn tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀ si kí wọn máa jáde láti wá sọ.

Sáájú ni àjọ ọlọ́pàá lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ṣàlàyé pé kò si ọlọ́pàá tó ni àṣẹ láti maa yẹ fóònù ẹnikẹ́ni wò lójú pópó láì ni ìwé àṣẹ ìjọba.

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa pada bẹrẹ igbesẹ lori ọrọ yii latari awọn ọmọ Naijiria to n gbe atẹjade Olumide lori Twitter ru ti wọn si n pin in kaakiri lori ayejlujara titi ti o ṣe to awọn ọga ọlọpaa leti.