Child marriage: Wo ọmọbìnrin ọdún méjìlá tó ṣè'gbéyàwó pẹ̀lú ọkùnrin méjì láàrin oṣù kan

Ọwọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Eemọ lukutu pẹbẹ. Ọmọdebinrin ẹni ọdun mejila kan lo ṣe igbeyawo tipatipa pẹlu ọkunrin meji laarin oṣu kan ṣoṣo.

Ba wo lo ṣe jẹ? Ilu Nairobi lorilẹede Kenya lo ma ti ṣẹlẹ, baba ọmọ naa to n gbe ni ẹkun Narok lapa iwọ oorun olu ilu Kenya lo kọkọ fi ọmọ naa fun ọkunrin kan ẹni ọdun mọkanlelaadọta.

Ọmọde yii moribọ nibi igbeyawo tipatipa ọhun, lẹyin naa ni baba rẹ tun fi fun ọkunrin mii to jẹ ẹni ọdun marundinlogoji.

Nile ọkunrin keji yii to ṣe igbayawo pẹlu rẹ lo wa ko ti wi pe ajọ ajafẹtọ awọn ọmọde kan gba a silẹ pẹlu atilẹyin awọn oṣiṣẹ ijọba kan.

Gbigbe ọmọbinrin ti ko ba to ọdun mehidinlogun niyawo lodi si ofin lorilẹede Kenya.

Adari ajafẹtọ fawọn ọmọde to doola ọmọdebinrin naa sọ pe ẹnikan lo ta oun lolobo nipa ọrọ ọmọ ọdun mejila naa lasiko ti oun n gbiyuanju lati doola ọmọde miiran.

Ọmọ ti wọn doola

Ọgbẹni Joshua Kaputah ni iṣẹ ati bi ijọba ti gbe ileewe tipa nitori ajakalẹ aarun coronavirus ti jẹ iṣẹlẹ ṣiṣe igbeyawo tipatipa fawọn ọmọde pọ sii.

''Ọpọ idile ni ebi n pa lasiko yii, ati pe maalu meji si mẹta ti wọn yoo gba gẹgẹ bi owo ori lo n mu ọpọ ṣe igbeyawo tulaasi fawọn ọmọde,'' Kaputah lo woye bẹẹ.

Akọroyin BBC to wa niluu Nairobi sọ pe ṣiṣe igbeyawo tipatipa fawọn ọmọde eyi to wọ pọ laarin awọn ẹya Massai lẹkun Narok n kọ ọpọ lominu lorilẹede Kenya

Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ti wa awọn baba ọmọdebinrin naa atawọn ọkun mejeeji to fẹ ni tipatipa laarin oṣu kan.

Ṣugbọn iroyin ti a gbọ ni pe awọn ọkunrin ti juba ehoro.