Seyi Makinde vs ALGON: Àwọn alága káńsù ní ìpínlẹ̀ Oyo fẹ́ pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí bígómìnà Seyi Makinde ṣe yọ wọ́n nípò

Oríṣun àwòrán, oyoinsight.com
Ni Ọjọru ni ileẹjọ kotẹmilọrun to fikalẹ si ilu Ibadan gbe idajọ rẹ sita lori ẹjọ to n waye lori bi ijọba ipinlẹ Ọyọ labẹ Gomina Makinde ṣe tu awọn igbimọ ijọba ibilẹ ka nibẹ.
Nibayii, Ẹgbẹ awọn alaga kansu ALGON ni ipinlẹ Ọyọ ti ṣalaye wi pe awọn yoo pe ẹjọ kotẹmilọrun lori idajọ naa niwaju ile ẹjọ to ga julọ lorilẹede Naijiria.
Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ lori idajs naa, alaga ẹgbẹ awọn alaga Kansu ALGON ni ipinlẹ Ọyọ, Ọmọọba Abass Alẹshinlọyẹ ni bi igba ti eeyan fẹ mọọmọ fi ọwọ ọla gba awọn alaga kansu naa loju lọrs ọhun yii.
O ni asiko to fun awọn gomina lati dẹkun aṣa pe awọn ko lee ba alaga kansu ti ko ba ti wa lati ẹgbẹ oṣẹlu wọn ṣiṣẹ. O fi kun pe ko si ibi ti ile ẹjọ naa ti sọ pe wọn ko dibo yan awọn nitootọ nitori naa ohun to tọna ni ki gomina Makinde fi aye gba awọn alaga kansu naa lati lo saa wọn eleyi ti yoo pari ni ọdun 2021.
Nigba to n dahun ibeere lori ohun to fa akude ba igbesẹ yiyanju aawọ naa ni tubiinubi eleyi to kskọ n waye laarin igun mejeeji, Ọmọọba Alẹshinlọyẹ ṣalaye pe gomina ijọba ipinlẹ Ọyọ n fi iwa jẹgujẹra lọ awọn lo faa ti awọn fi yọwọ-yọsẹ ninu igbesẹ naa nigba naa.
O ni ohun ti ijọba ipinlẹ Ọyọ n gbero lati ṣe nigba naa ni lati san owo fun awọn alaga kansu naa ki wọn si maa lọ eleyi ti wọn ni awọn kọ jalẹ nitori loju awọn bii igba ti awọn gba owo iṣẹ ti awọn ko ṣe ni eyi, iwa jẹgudujẹra si ni.
Makinde ré àwọn alága káńsù lẹ́fásẹ̀ nílé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rún n'Ibadan

Oríṣun àwòrán, twitter/Seyi makinde
Ile ẹjọ kotẹmilọrun ni ilu Ibadan ti gbe idajọ kalẹ pe ko sohun to buru ninu igbesẹ Gomina Seyi Makinde lati tu awọn ijọba ibilẹ ka ni ipinlẹ Ọyọ.
Onidajọ Haruna Tsammani to gbe idajọ naa kalẹ gbẹsẹle idajọ ti ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ gbe kalẹ ni ilu Ibadan leyi to ti ni Gomina Makinde tasẹ agẹrẹ lori igbesẹ naa, pe ko bofin mu.
Onidajọ Tsammani ṣalaye pe ori ahesọ ati gbọyisọyi ni awọn alaga kansu ti wọn rọ loye naa gbe ipẹjọ wọn naa le.
Bashorun Bọsun Ajuwọn lo pe ẹjọ ọhun lorukọ awọn alaga kansu naa.
Itaporogan laarin gomina Makinde atawọn alaga kansu labẹ aṣia ALGON ni ipinlẹ Ọyọ bẹrẹ ni kete lẹyin ti wọn bura wọle sipo fun Makinde gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọyọ.
Gomina Makinde tu awọn igbimọ iṣejọba ibilẹ ni ipinlẹ naa ka lori ẹsun pe ilana ti wọn fi de ipo tako ofin.
Labẹ gomina ana ni ipinlẹ Ọyọ, oloogbe Abiọla Ajimọbi ni wọn ti yan awọn alaga kansu naa ki Gomina Makinde to tu wọn ka ni wakati diẹ lẹyin to gori oye.













