Ebila of Ibadan: Ikọ̀ Operation Burst" ní àwọn ló pa Ebila, olórí àwọn "One million boys" n'Ibadan

Abiola Ebila

Oríṣun àwòrán, others

Ọga agba ikọ agboguntiwa ọdaran ni ipinlẹ Ọyọ eyi taa mọ si Operation Burst, Kọnẹẹli Ọladipọ Ajibọla ti ṣalaye pe ikọ naa lo ṣekupa olori awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun One million boys ni ipinlẹ Ọyọ, Abiọla Ebila lọjọ Aiku.

Ọgagunfẹyinti Ọladipọ Ajibọla ni ara igbesẹ lati dẹkun iwa ọdaran awọn ẹgbẹ ọdaran abi ẹgbẹ okunkun to n da họwuhọwu silẹ ni ipinlẹ Ọyọ ni o ṣokunfa iku Ebila.

Nigba ti o n ṣalaye bi wọn ṣe pa aṣiwaju ẹgbẹ okunkun naa, Kọnẹẹli Ọladipọ ni, yatọ si pe wọn yinbọn pa Ebila lasiko to fi n gbiyanju lati sa mọ awọn agbofinro lọwọ leti bebe odo Kudẹti, awọn ni ẹri pe ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun onemillion boys to wa pẹlu rẹ naa fi ara gbọta ibọn.

O ni awọn agbofinro ikọ Operation Burst fẹ lọ doola eeyan kan tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa kan ji gbe ni wọn fi fija pẹẹta ti itaporogan ibọn si waye leyi to ṣeku pa Ebila tawọn miran si tun fara gbọta.

O ni bi o tilẹ jẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun naa kan gbe oku Ebila lọ, sibẹ awọn lee sọ pe ẹkọ ṣoju mimu nibi ikọlu naa nitori pe awọn ri ẹni ti wọn ji gbe naa gba pada, ti wọn si tun ṣọṣẹ si ẹgbẹ okunkun naa.

Àkọlé fídíò, 'Ó ṣe pàtàkì kí obìnrin gbádùn ìbálòpọ̀ nítorí...'

" Awọn alami kan lo ta wa lolobo pe awọn kan ji eeyan kan gbe pamọ sinu akọku ile kan lagbegbe Kudẹti.

Alami naa ṣalaye fun wa pe mẹta ninu awọn ọmọlẹyin Ebila ji eeyan kan gbe ni ikọ operation Burst ba ko sẹnu i'sẹ lọgan nitori awa pẹlu ti mọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun One million boys ti sọ ara wọn ikan ti n jẹle lagbegbe naa.

Ni kete ti wọn ri wa, awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun one million boys ba bẹrẹ si ni yinbọn, nibi ti awa pẹlu naa ti ṣina ibọn bolẹ fun wọn ni a ti pa Abiọla Ebila, ti a si wọ inu akọku ile naa lọ nibi ti a ti ri ẹni ti wọn ji gbe naa ti orukọ n jẹ Olufẹmi Awogboro ti a si doola ẹmi rẹ."

Awọn operation burst

Oríṣun àwòrán, others

Ni tirẹ, kọmiṣọna ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Nwachukwu Enwonwu ṣalaye pe awọn ọlọpaa kọ lo pa Ebila ati pe lati ọjọ kọkanla oṣu kẹrin ọdun yii ni wọn ti n wa Ebila lori iku Moshood Ọladokun ti ọpọ mọ si Ẹkugbemi to jẹ olori ẹgbẹ okunkun miran nilu Ibadan.