Nigeria Air Force recruitment 2020: Ilé iṣẹ́ ọmọogun Nàìjíríà ti ṣí ojú opó rẹ̀ fún ìforúkọ silẹ̀ àti ọ̀nà ti ó le gbà ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ̀nuwò orí ayélujára fún iṣẹ́ náà

Igbaniṣiṣẹ ọmọogun ojú ofurufu fún ọdún 2020

Oríṣun àwòrán, Nigeria Airf Force

Ilé iṣẹ́ ọmọ ogun òfurufú ti ṣi ojú òpó wọ́n fún ìforúkọ̀silẹ̀ àti ìgbaniasíṣẹ́ fún àwọn obinrin àti ọkùnrin,

tó fẹ́di ọmọogun ojú òfurufú bí orílẹ̀-èdà Nàìjíríà ṣe n ṣelédè lẹ́yìn obìnrin akọ́kọ́ tó n wa ẹlikọputa ọmọogun Tolulope Arotile bí ó ṣe wọ káàlẹ̀ sùn.

Báyìí ni Arotile náà ṣe bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjo to sọ di olókìkí nìgbà to fi orúkọ silẹ̀ láti ṣe iṣẹ́ yìí ni ọdún díẹ̀ sẹ́yìn.

Ọjọ́ kẹrinlélógùn ọsù kèje ni ilé iṣẹ́ náà si ojú òpó rẹ̀ fún gbogbo ẹni to ba fẹ́ gba iṣẹ́, ọjọ́ kan lẹ́yìn tí wọ́n sin Tolulope Arotile.

Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ni ẹka ọmọgun to ń lo bàlùú, ẹlikọpta àti àwọn irinṣẹ́ miran ti wọ́n fi ń fò láti dáàbò bo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lókè

Ìgbaniṣíṣẹ́ ti ọdún 2020 jẹ́ ti ẹ̀kọ́ Basic Military Training (BMTC) tí sílẹ̀ fun gbogbo éni to ba ti jẹ́ ọmọ bíbí Nàìjíríà, tí sì yóò si pari ni ọjọ́kọkanlélógún oṣù kẹjọ ọdún 2020.

Bí o ṣe le fi orúkọ silẹ̀ láti darapọ̀ Nigeria Air Force

  • Ẹni tó ba wù ti o si ni gbogbo ǹkan to nilò lati f'orúkọ silẹ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tabi ki ó ló èyí www.airforce.mil.ng
  • O nì nílò láti san kọ́bọ̀, ọ̀fẹ́ ni
  • Ẹ̀ẹ̀kan péré ni o le fi orúkọ silẹ̀; bi o bá gbìyànjú lati ṣee lẹẹmeji, wọ́n yóò wọ́gile.
  • O gbọdọ̀ ṣe ẹ̀dà iwé yìí ti o ba ti forúkọ silẹ tan lóri ayélujara: (a) Iwe ti o fi han ọmọ ipinlẹ ti o jẹ́; (b) Alága ìjọba ìbilẹ̀ rẹ̀ gbọdọ̀ tọ́wọ́bọ̀wé ìjẹ́ri si tabi ọgá ológún kan (d). Iwe mo mọ si ti wọ́n ti tọ́wọ́bọ̀ náà gbọ̀dọ̀ wá láti ọ̀dọ́ òbí tàbi alágbà tọ́ rẹ
Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ti bẹ̀rl ètò ìgbaníwọlé- Àwọ ìlànà ìforúkọsilẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Nigerian Air Force

Àwọn ǹkan ti o gbọdọ ni

  • O gbọ́dọ jẹ́ ọmọ Naijiria nípa ìbí.
  • O gbódọ ga ju ìwọ̀n bàtà 1.66m lọ gẹ́gẹ́ bi ọkùnrin nígbà ti obinrin gbọdọ jẹ́ 1.663m
  • O gbọdọ pé lẹ́mìí àti ni àra.
  • Olùforukósilẹ̀ ko gbọdọ̀ ni àkọsilẹ̀ ìwà ọ̀daràn níle ẹjọ.
  • Àwọn Non Tradesmen/Women kò gbọdọ ju ọmọ ọdún méjìdinlógun si ọmọ ọdún méjìlélógún lọ, ní ọgbọ̀n ọjọ ọsù kẹfa ọdún 2021
  • O gbọdọ ni o kéré tan ami kare marun to fi mọ ìṣirò àti gẹẹsi níjoko ẹ̀ẹ̀meji nínú SSCE/NECO/ GCE/NABTEB
  • Fún ti Tradesmen/Wome: (a) Olùforukọsilẹ̀ gbọdọ̀ wà láàrin ọdun méjidílógún sí márùndínlọ́gbọ̀n àfi àwọn to bá fẹ́ gbá oye Chaplain/ Imaams àti Awakọ. Ọjọ́ ori ti wọn yóò maa wà láàrin ọdún méjìdínlógun sí méjìdílọ́gbọ̀n; (b) Wọ́n gbọdọ̀ ní amí kare nínú ND tabi NCE tabi trade test lati àwọn ilé iṣẹ́ ti ìjọba fọ́wọ́ sí, o kéré tan ninu iṣẹ́ meji ati kírẹ́dítì fun èdè gẹ̀ẹ́sì.
  • Tó ba jẹ́ pé eré ìdáraya lókùnrin ati lobinrin ló fẹ́ fi orúkọ silẹ̀ fún, o gbọdọ̀ sàfihan iwe ẹri pé iṣẹ́ ti ó yàn láàyò ni, iwé ẹ̀rí àti awọn àmì ẹ̀yẹ ti ti gbà gọds wà níbl pẹ̀lú.
Ilé iṣẹ́ ọmọogun òfurufú ti bẹ̀rl ètò ìgbaníwọlé- Àwọ ìlànà ìforúkọsilẹ̀ rèé

Oríṣun àwòrán, Nigeria Air Force

Àwọn kókó tó ṣe pàtàkì

  • Ìfórúkọsilẹ̀ orí ayélujára bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ kẹrinlélógun yóò si kágbá nílẹ̀ kọkànlélógún oṣù kẹjọ ọdún 2020.
  • Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún ìgbàniwọlé yóò wáye ni ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹ̀sán ọdún 2020 sí ọjọ́ kejìlá oṣù kọkànkánlá ọdún 2020.
  • Ọ̀fẹ́ ni ìforúkọsílẹ̀ fún iṣẹ́ ọmọogun òfurufú yìí àti àwọn míràn lórí ayélujara, olùforukọsilẹ̀ kò si ni san owó kankan láti ìbẹ̀rẹ̀ titi de òpin.
  • Ìwé ti wọ́n yóò fọ́wọ́sí láti ìjọba ìbílẹ̀ gbọdọ wá pẹ̀lú fótò pélébé ẹni ti ó tọwọ́ bọ̀wé, ẹ̀dà fọ́tò iwé ìrìnà ọ̀kọ̀, káàdì ìdánimọ̀ ìjọba àpapọ̀ tàbí ìwé ìrìnà lọ si ilẹ̀ òkèrè.
  • Fún àlàyé sii lọ sí ojú òpó Nigeria Airforce tabi kí o pe àwọn nọmbá yìí láàrin aago mẹ́sàn àbọ̀ òwúrọ̀ sí aago márùn àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ láti ọjọ́ ajé sí ọjọ́ jímọ̀ 08043440802 and 09055840142 tabi ki o kọ̀wé ránṣẹ́ si ibi yìí e-mail: [email protected]
Àwọn ọmọogun ojú òfurufu dúró siwaju ọkọ̀ ofurufu ti wọ́n fi n jágun

Oríṣun àwòrán, Nigerian Air Force

Àkọlé àwòrán, Àwọn ọmọogun ojú òfurufu dúró siwaju ọkọ̀ ofurufu ti wọ́n fi n jágun
Grey line wey dey

Kini BTMC?

Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tó wà lórí ayélujára ilé iṣk ọmọogun òfurufú, wọ́n ni ẹ̀kọ́ náà jẹ́ ti ọlọ́ja kúkúrú fún àwọn ọkùnrin àti obinrin tọ ṣíṣẹ́ ofurufú, tí kò sì ni ju oṣù mẹ́fà lọ lati fi gba ẹ̀kọ́.