Nigerian Youth Investment Fund: Ijọba àpapọ̀ yóò kó bílíọnù 75 owó ẹyá fún àwọn ilé ìfowópamọ́ kéékèké fún ìṣòwò àwọn ọ̀dọ́

Nigerian Youth Investment Fund NYIF

Oríṣun àwòrán, Sunday Dare

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Níní ìwádìí àjọ "International Labour Organization" tó jẹyọ lọ́dún 2019, ìdá àwọn ọ̀dọ́ tí kò níṣẹ́ lápa ní Nàìjíríà jẹ́ ìdá mẹ́rìnlá

Bákan náà ni ìjọba orílẹ̀-èdè Nàìjíríà náà tún fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti kò niṣẹ́ lọ́wọ́ ni Nàìjíríà jẹ́ ìdá mẹ́tàlélọ́gbọ̀n àbọ̀ ní ọdún 2020.

Lójùnà àti mójú tó ìpèníjà yìí, Aàrẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu owó bílíọ̀nù márùndinlọ́gọ́jọ náírà láti bẹ̀rẹ̀ ilé iṣẹ́ ti yóò maa ri sí ọ̀nà ti àwọn ọdọ́ tó bá ni ǹkan ti wọ́n fẹ́ ṣe lọ́kan yóò ṣe ri owó tí wọ́n yóò maa fi ṣe owo ti wọ́n sì pe orúkọ rẹ̀ ní Nigeria Youth Investment Fund (NYIF).

Àkọlé fídíò, Peters Ijagbemi dá àrá lórí ètò 'Ṣé o láyà' ti BBC Yorùbá lọ̀sẹ̀ yìí

Ìbúwọ́lù ọ̀hún wáyé lẹ́yìn ti mínísítà fún ọ̀rọ̀ ọdọ́ àti eré ìdarayá ṣe àgbékalẹ̀ iwé kan lásìkò ìpàdé àwọn ìgbìmọ̀ àláṣẹ ìjọba àpapọ̀ níbi tó ti sàlàyé bi ọ̀rọ̀ ajé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà yóò ṣe ri ti ìjọba bá ṣe ètò tó yẹ lórí àwọn ọdọ́.

Mínísítà fun àwọn ọdọ́ ṣe afilọ́lẹ̀ ètò DEEL fún àwọn ọdọ́ Naijiria nílù Abuja ninu oṣù kọkanlá, ọdún 2019

Oríṣun àwòrán, SUNDAY DARE/TWITTER

Àkọlé àwòrán, Mínísítà fun àwọn ọdọ́ ṣe afilọ́lẹ̀ ètò DEEL fún àwọn ọdọ́ Naijiria nílù Abuja ninu oṣù kọkanlá, ọdún 2019

Mínísítà fún ọ̀dọ́ àti eré ìdárayá sọ pé ètò owó idokoowò náà yóò dabi ilé ìfowópamọ fún àwọn ọdọ́ láti le maa yáwó fun okoòwò wọ́n.

Tí ọ̀dọ́ bá ni okoòwò kan ti ó ṣe kówólé, àwọn ilé ifowópamọ́ kéèké to wà lọ́bẹ́ Banki àpapọ̀ Naijiria (CBN) yóò fún wan lọ́wọ́ láti bẹ̀rl okoòwò náà.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Báwo ni ètò 'Nigeria Youth Investment Fund' yóò ṣe ṣiṣẹ́

Gẹ́gẹ́ bi mínísítà ṣe sọ, ètò "Nigeria Youth Investment Fund" kìí ṣe iṣẹ́ ti àwọn ènìyàn yóò ma gba owó oṣù, tàbi ìrọgùn sápá tàbi ètò adájútòfò kankan ti ìjọba ti ṣe tẹ́lẹ̀,

O ṣalaye pe èyí yàtọ̀ gédégédé, yóò maa fún àwọn ọ̀dọ́ láànfàní láti le bẹ̀rl okoòwò wọ́n, láì ṣiṣẹ́ lábẹ́ ẹnikẹ́ni.

O gbọ̀dọ ni èrò okoòwò ti o ṣee kówó lé lóró, ti o ṣe fòye gbé ti ó sì ṣee ṣe.

ìjọba náà ń gbìyànjú ni láti kó owó yìí kalẹ̀, èyí ni ìgbà àkọkọ ti ìjọba yóò fórí lá ewu nítori àwọn ọ̀dọ́,ànfani rèé fún ọ̀dọ́ láti ṣe oríire.

Mínísità fún ọ̀dọ́ àti ìdàgbásókè eré ìdáraya, Sunday Dare

Oríṣun àwòrán, SA MEDIA MINISTRY OF YOUTH AND SPORT DEVELOPMENT

Àkọlé àwòrán, Mínísità fún ọ̀dọ́ àti ìdàgbásókè eré ìdáraya, Sunday Dare

Ilé iṣẹ́ ọdọ́ àti ìdàgbàsókè eré ìdáraya ti bẹ̀rẹ̀ ètò lórí bi àwọn ilé ìfowópamọ́ ọ̀dọ́ yìí yóò ṣe bẹ̀rẹ̀,

Bákan náà ni gbogbo iwé ofin ti yóò gbe e dúró ti n lọ lọ́wọ́.

Yatọ si eyi, wọ́n ń fọ́wọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ilé ìfówópamọ ìjọ́ba àpapọ̀, (CBN) pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ìṣúná tó fi mọ́ àwọn ajọ míràn láti wá owó ti wọn yóò fi bẹ̀rẹ̀ ètò ọhun.

Àkọlé fídíò, Working religious women: Ẹ̀lẹ́hàá kìí ṣe ọ̀lẹ- Aminat Adegoke

Sunday Dare ní òun ní ìgbàgbọ́ pé ètò náà yóò bẹ̀rl ni ọsẹ̀ àkọ́kọ́ nínú oṣù kẹ̀sán ọdún 2020 àti pé àfojúsùn ní láti ri ọ̀dọ́ to tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta láti fi orúkọ silẹ̀ fún ọdún àkọ́kọ́ .

Eyi ko ṣẹyin níwọ̀n ìgbà tó jẹ́ pé ọdún mẹ́ta ni ètò náà yóò fi kọ́kọ́ wà.

O ní wọn yóò pín bílíọ̀nù mọárùndínláàdọ́jọ náà si ọ̀nà mẹ́ta ni ti yóò sì jẹ́ bílíọ̀nù márùdínlọ́gbọ̀n fún ọdún kọ̀ọ̀kan.

Eto idokoowoo awọn ọdọ

Oríṣun àwòrán, SUNDAY DARE/TWITTER

Àkọlé àwòrán, Eto idokoowoo awọn ọdọ

Àwọn ti o yóò jànfani yìí yóò ni ẹ̀tọ́ si ẹgbẹ̀rún lọ́nà ààdọ́ta lé ni igba náírà sí àádọ́ta mílíọ̀nù náirà ti wọ́n yóò sì maa san elé ìdá marún un lórí owó ti wọ́n bá yá. wọn le jẹ ọlọ́dani tàbi ki wọ́n jẹ́ ẹgbẹ́.

Ǹkan ẹyọ kan ni owó yìí wà fún, ǹkan náà si ni láti fi gbárùkù ti ìdókoowo ti ènìyàn bá fẹ́ ṣe tàbi láti fi ran ẹni to ni ẹ̀bùn kán tó sì nílò owó láti gbé ẹ̀bùn náà jáde, àti pé àwọn ọ̀dọ́ nìkàn ni ó wà fún.

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Eto D Royal African Leadership Forum ti Arole Oodua Ooni Ife ṣe agbátẹru rẹ̀

Oríṣun àwòrán, SUNDAY DARE/TWITTER

Àkọlé àwòrán, Eto D Royal African Leadership Forum ti Arole Oodua Ooni Ife ṣe agbátẹru rẹ̀

Tani ó tọ́ sí àti pé báwo ni o ṣe le fi orúkọ sílẹ̀ fún ètò Nigeria Youth Investment Fund

O yẹ ki ètò náà bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù kẹ̀sán nítori náà àwọn ǹkan ti àwọn ọ̀dọ́ yóò nílò rèé láti fi orúkọ silẹ̀ fún ètò náà.

  • Olùforukọsilẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ ọmọ orilẹ̀-èdè Nàìjíríà, ọjọ́ ori rẹ sì gbọdọ̀ wà láàrin ọdún méjìdínlógún sí márùndínlogójì
  • O gbọdọ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ jáde kí o si ti sín ilẹ̀ baba rẹ̀.
  • Àwọn ti wọ́n kò lọ ilé iwé gbọdọ́ ni ǹkan ti a fi n dáni mọ
  • Olùforúkọ silẹ̀ gbọdọ ti kọ iwé ti yóò sàlàyé, bí okoòwò náà yóò ṣe ri, iye èrè ti yóò wà nibẹ̀, owó ti yóò to láti bẹ̀rẹ̀, àti èrèdi ti o fi fẹ́ ṣe iṣẹ́ náà.
  • Ọ̀dọ́ náà gbọdọ́ mú iṣẹ́ ti ó ṣe kówó le lórí.
  • Káàdì ìdánimọ̀ ]ijọba apapọ̀, káàdì ìfọ́rukọsilẹ̀ fún ìdìbò tàbi káàdì ìrìnajò lọ ilẹ̀ òkèrè
  • Onídúró kan
  • Ilé iṣẹ́ ti o ti fi orúkọ rẹ̀ silẹ̀
  • Nọmba ìdánimọ ti Banki (BVN)

Àwọn ilé iṣk ti ọ̀rọ̀ náà kan ṣì n foríkori lati rii dáju pé ètò náà kò nira bi ìgbà ti ènìyàn bá fẹ ṣe ẹyáwo ni banki Nàìjíríà.

Àkọlé fídíò, Itan Ilu gangan