N-Power 2020 recruitment: Ṣé lóòtọ́ ní pé àwọn alákòso tí kéde àwọn tó ṣe àṣeyọrí nínú ètò ìgbanisíṣẹ́ ọdún 2020?

Oríṣun àwòrán, NPower
Awọn to n ṣeto irọkun sapa awọn ọdọ Naijiria ti a mọ si N-Power ti sọrọ nipa iroyin to gbode nipa awọn ti wọn ti ya orukọ wọn sọtọ f'abala keji igbanisiṣẹ eto naa lọdun 2020.
Ileeṣẹ to n ṣeto ọrọ eeyan ati iṣẹlẹ pajawiri to jẹ agbatẹru eto naa ni iroyin ofege ni iroyin yi.
Nitorin naa wọn fi ikilọ sita loju opo wọn ni Twitter ki awọn eeyan sọra fawọn onijibiti to n gbe iroyin ẹlẹjẹ yi ka.
- Ààrẹ Muhammadu Buhari gbè sẹ́yìn Keyamo lórí ètò ìṣẹ́ 774,000
- Bí o ṣe lè forúkọ silẹ̀ fún ètò "N75BN Nigerian Youth Investment Fund" rèé...
- Nigeria Police Recruitment 2020: Àwọn ohun tí ẹ nílò fún àyẹ̀wò ìgbanisíṣẹ́ ọlọ́pàá tí yóò bẹ̀rẹ̀ ní Mon, Aug 24
- Èsì ìdánwò òhun tí a ṣé síwájú là n bá fínra báyìí ní Nàìjíríà- Yemi Shodimu
Ileeṣẹ ọhun sọ pe nigba to ba ya awọn yoo fi ikede sita gba ojulowo opo wọn lori ayelujara.
Lọjọ Kẹsan an, oṣu Kẹjọ ni gbedeke fifi iwe ranṣẹ loju opo N-power wa sopin lẹyin ti wọn ti gba iwe awọn to n wa iṣẹ to le ni miliọnu marun un lọ.
Iwadii BBC ṣafihan pe ileeṣẹ ijọba to n ṣakoso N-Power ti bẹrẹ si ni ṣe agbeyẹwo awọn to fiiwe ranṣẹ bẹẹ naa ni wọn ni gbiyanju lati yanju ajẹsilẹ owo awọn to kopa ninu abala ikini ati ikeji eto naa to wa nilẹ.
- Ibi ọ̀rọ̀ dé dúró lórí ṣíṣí àwọn ilé ìwé padà ní Naijira rèé àti nílẹ̀ Afrika
- Òpópónà àti afárá 19 níjọba fẹ́ ṣe nínú àbá ìṣúná ọdún 2020
- A wà nínú igbó tí a ti ń wá àwọn arinrìnàjò mẹ́jọ láti Abuja sí Eko tí wọ́n jígbé lọ- Ọlọ́pàá Ondo
- E wo ọmọ Yorùbá àkọ́kọ́ tó jà fún ẹ̀tọ́ àwọn aláwọ̀dúdú ní America!
Lọjọbọ, Minisita to n dari ileeṣẹ yi, Sadiya Umar sọ nibi apero kan to waye ni Katsina pe awọn ti yan awọn eeyan kan ti ijọba ipinlẹ yoo le ba ṣiṣẹ pọ lori awọn eto gbọnṣẹ gbọnyanu ijọba apapọ bi N-Power, Market-Moni ati Conditional Cash Transfer.
Afojusun awọn eto yi gẹgẹ bi ijọba ti ṣe sọ ni ki wọn ba le mu adinku ba iye awọn ti ko niṣẹ lorile-ede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, @NPOWER_NG TWITTER
Bí o bá ń se N-Power tóo sì ti ríṣẹ́ sí ibòmíràn, olè ni ọ́! - Ìjọba àpapọ̀
N-Power jẹ ọna ti ijọba n gba pese isẹ fun awọn ọdọ, labẹ ẹka ijọba to n ri si eto amuludun ati irọkun sapa awọn ara ilu.
Ilẹ isẹ ijọba apapọ lori amojuto ara ilu, mimoju to ajalu idagbasoke eto amuludun ti salaye pe ẹnikẹni ti ko ba tii gba ajẹmọnu tirẹ tumọ si pe orukọ ẹni bẹẹ wa ni ile iṣẹ ijọba apapọ miran ni.
Eyi ni o jẹyọ ninu atẹjade ti ile iṣẹ naa fi sita ti igbakeji adari ile iṣẹ naa Rhoda Ishaku Iliya si buwọlu lọjọbọ.
Ile iṣẹ naa ni awọn ti fi orukọ awọn ẹgbẹrun to le ni ẹẹdẹgbẹta awọn to wa labẹ eto N- Power sọwọ si ofiisi akọwe owo ijọba ati ti awon ẹgbẹrun mejilelẹẹdẹgbẹta naa si ti ri owo wọn lati ori eto GIFMIS ti ijoba la silẹ lati maa fi san owo ọhun.
Wọn fi kun un pe àwọn bi ẹgbẹrun mẹrinla to ku ti ko ri owo gba tumọ si pe orukọ wọn pada ni, nitori pe orukọ wọn ti jẹyọ nile iṣẹ ijọba apapọ miran eyi si lodi si ofin N-Power.
Minisita ile iṣẹ naa Sadiya Umar Farouq rawọ ẹbẹ si ẹnikẹni ti o ba jẹ ojulowo N-Power ti ko si ri owo naa gba lati fọwọ wọnu.
Ki lo ti ṣẹlẹ sẹyin?
N-Power 2020 recruitment: Àwon ohun tó yẹ kí o mọ̀

Oríṣun àwòrán, N-POWER 2020 REGISTRATION
Wo àwon ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ètò ìgbanisíṣẹ́ N-Power ọdún 2020
Ọpọ awọn eeyan lo ti n bere ohun ti wọn nilo lati ṣe iforukosilẹ fun eto igbanisiṣẹ N-Power ọdun 2020.
O ti le ni miliọnu kan eeyan to ti forukọ silẹ fun eto igbanisiṣẹ naa.
Eyii ni awọn ohun to yẹ ki o mọ ti o ba fẹ ṣe iforukọsilẹ fun eto ọhun.
Ṣe iforukọsilẹ N-power ti ọdun 2020 ti bẹrẹ?
Idahun: Bẹẹni, o le e lọ forukọ silẹ bayii ti o ba nifẹ si eto igbanisiṣẹ naa.
Isọri melo lo wa ninu eto naa?
Idahun: Isọri mẹta to wa ninu N-power ọdun 2020 ni N-Power Knowledge, N-Power Volunteer ati N-Power build.
Elo ni owo ti awọn oṣiṣẹ labẹ N-Power yoo ma gba loṣoṣu?
Idahun: Isọri owo oṣu N-power ree loṣu:
N-Power Teach: ₦28,000 - si ₦30,000 loṣu.
N-Power Agro: ₦25,000 - si ₦30,000 loṣu.
N-Power Health: ₦30,000 - si ₦40,000 loṣu.
N-Power Community Education: ₦10,000 - si ₦30,000 loṣu.
N-Power Creative: ₦10,000 - si ₦30,000 loṣu.
N-Power Tech (Software): ₦20,000 - si ₦40,000 loṣu.
N-Power Tech (Hardware): ₦20,000 -si ₦40,000 loṣu.
N-Power Build: ₦27,000 - si ₦30,000 losu.

Oríṣun àwòrán, @NPOWER_NG TWITTER
Iye eeyan meloo ni N-Power fẹ gba siṣẹ lọdun 2020?
Gẹgẹ bi awọn oludari eto naa ṣe sọ, ẹgbẹrun lọna irinwo eeyan ni N-Power n mura lati gba siṣẹ ni ababla kẹta yii.
Ṣugbọn o ti le ni miliọnu kan eeyan to ti forukọ silẹ fun eto ọhun lọdun yii.
Eeyan melo ni ijọba apapọ ti gba siṣẹ labẹ asia N-Power ṣaaju?
Lọdun 2016, ijọba apapọ gba ẹgbẹrun lọna igba eeyan siṣẹ labẹ asia N-Power, bẹẹ lo tun gba ẹgbẹrun lọna ọọdunrun eeyan mii lọdun 2017.
Lẹyin ti wọn ba ti lo ọdun mei ninu eto naa, ijọba yoo tun gba isọri awọn ọdọ miran siṣẹ labẹ asia eto ọhun.
Awọn wo ni N-power Agro wa fun?
N-power Agro wa fun awọn to nifẹ lati kọ nipa iṣẹ agbẹ, ti wọn yoo si le da wa laye ara wọn lẹyin ti wọn ba ti pari eto naa tan.
N-Power build nkọ?
Awọn to fẹ kọ ẹkọ nipa bi wọn ṣe n kọ awọn nnka bi ile, bi wọn ṣe n tu ọkọ sẹ, ati bẹbẹ lọ ni N-Power build wa fun.
Ẹgbẹrun márùndínlọ́gọ́rin awọn ọdọ ti ko ni iṣẹ lọwọ ni yoo jẹ anfani eto ọhun.
Igba wo ni N-power bẹrẹ?
Ọdun 2016 ni ijọba apapọ Naijiria bẹrẹ eto N-Power, ti eeyan to to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta si ti jẹ anfaani rẹ.















