Delta petrol tanker explosion: O ti lé ní ènìyàn mẹ́wàá tí ina jó gúrúgúrú nínú ìjàmbá tó wáyé ní Delta

O le ni eniyan mewaa ti ina jo guruguru ninu ijamba ọkọ.
Awọn eniyan ku nigba ti ọpọ farapa nibi ijamba ọkọ epo petiro to waye ni ipinlẹ Delta ni ẹkun Guusu-guusu Naijiria.
Gẹgẹ bi awọn ti ọrọ naa soju wọn se sọ, o kere tan eniyan ogun lo jona guruguru ti wọn ko se damọ nibi iṣẹlẹ naa ṣugbọn awọn ọlọpaa sọ pe oku eniyan mẹta lo jona julọ ti ko ṣee damọ mọ rara.
- Ṣé lóòtọ́ ni pé Hushpuppi ti kúrò ní ọgbà ẹ̀wọ̀n l'America? Ẹ wo àbájáde ìwádìí wa
- Donald Trump ti gbà pé Coronavirus yóò burú jáì kí ǹkan tó dára fún Amẹ́ríkà
- Wo bí ètò ìsìnkú Tolulope Arotile ṣe lọ nílùú Abuja
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Kano tí wọ́gilé ayẹyẹ lẹ́yìn ìrun ọdún Iléyá!
- Èmi Ọba tí wọ́n ń kó jẹ nígboro- Oluwo ti ilú Iwo
Wọn ni ọkọ epo ọhun subu ni orita meta Koko ni opopona Benin- Sapele nigba to n gbiyanju lati sa fun koto laarin ọna ọhun
Iroyin sọ pe, iṣẹlẹ naa waye ni nkan bi aago mọkanla owurọ yii, lẹyin ti ọkọ epo naa subu lo bẹrẹ si ni jo epo inu rẹ, bẹẹ lawọn eniyan lọ sibẹ lọ maa gbọn epo, bayii ni ina bu gbamu.

O kere tan moto mẹwaa lo jona nibẹ ti ọpọ dukia si ṣofo ninu awọn ọkọ naa.
Elomiran ti ọrọ naa tun soju rẹ ni awon eniyan to wa ninu mọto to jona nigba ti ina bu gbamu ni awọn to ku ati awọn to farapa.
Awọn alafojuri ni bi Tanka epo naa ṣe yi danu ni awọn eeyan kan sare sibẹ lati gbọn epo ko to gbina.
- Ta ni Yusuf Satia ti iku mu lọ?
- Ilé Aṣòfin yóò pe Godswill Akpabio l'ẹ́jọ́ fún ìbanilórúkọ jẹ́
- Kí ló pa Bobrisky àti Olorì Aláàfin Oyo pọ̀?
- Ọmọ Yorùbá mẹ́wàá tó jẹ́ àmúlùúdùn ní Amẹ́ríkà àti Yúróòpù
- Èèyàn 38,344 ló ti ní COVID-19 ní Nàìjíríà lẹ́yìn tí 543 kún un lọ́jọ̀rú
- Eyitayọ Jegede (PDP) ló máa gbéná wojú Rotimi Akeredolu (APC) nínú ètò ìdìbò Ondo tó ń bọ̀!
Ogbeni Charles Aniagwu to jẹ agbẹnusọ fun ijọba ipinlẹ Delta ṣalaye fun BBC pe ijanu ọkọ naa ja mọ awakọ naa lọwọ lasiko to n yago fun koto loju titi naa ni ti o si fa ijamba ọhun.
O ni bi epo naa ṣe yi danu sinu awọn koto ati loju titi ni awọn eeyan lọ n gbọn ọn ko to lana to si di akoba fun awọn ọkọ miran lori titi naa.
Ọpọ igba ni opopona Naijiria ti ko dara ti ṣokunfa ijamba ọkọ ni eyi to ti mu ẹmi awọn eeyan to pọ lọ si ọrun aremabọ.












