Ondo Kidnap: Ọlọ́pàá Ondo ní àwọn ti rí ẹníkan padà nínú mẹ́jọ tí wọ́n ń wà nínú ọkọ̀

Oríṣun àwòrán, Others
Ileeṣẹ Ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo ti ni aigbọran awọn eniyan lati ma ṣe rin irinajọ lasiko arun Coronavirus yii lo fun awọn ajinigbe lagbara lasiko yii.
Eyi ko ṣẹyin bi awọn ajinigbe tun ṣe ṣe ikọlu si ọkọ Toyota Sienna to gbe awọn eniyan mẹjọ to n lọ lati ilu Abuja si Eko ni Ọjọru.
Agbẹnusọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro lo fidi ọrọ naa mulẹ fun BBC Yoruba pẹlu alaye lori ibi ti ọrọ dee duro.
.
Ikoro ni awọn agbebọn naa ji wọn gbe ni agbegbe ijọba ibilẹ Isua-Akoko ni ipinlẹ Ondo.
O fikun un pe ohun ti awọn ajnigbe naa ṣe ni pe wọn yinbọn lu ọkọ naa, titi ti ko fi le rin mọ, ki wọn to wa ji wọn gbe.
Ikoro ni wọn ti doola ẹmi eniyan kan ninu awọn ti wọn jigbe naa, ti wọn si ti ri ọkọ naa gba pada.
O ni ikọ ọlọpaa, awọn ọmọ ogun Naijiria ati ajọ eleto aabo NSCDC ti wa ninu igbo lọwọlọwọ bayii ni ibi ti awọn ti n wa awọn meje to ku ninu ọkọ naa.

Oríṣun àwòrán, Others
Wọn ni igbagbọ pe awọn yoo ri wọn gba pada, ti o si ni ileeṣẹ ọlọpaa ko mọ nipa owo itanran ti iroyin ni wọn n beere fun.
Agbẹnusọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro naa parọwa si awọn eniyan lati tẹle ofin ijọba pe ki awọn eniyan ma rin irinajo lati ilu kan si ọmiran nitori itankalẹ arun Coronavirus lasiko yii.
Ikoro ni pe oju ọna to da paroparo fun awọn ajinigbe laaye lati ṣọṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Others
Amọ, Agbẹnusọ awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Ondo naa wi pe awọn ọlọpaa kaakiri ni Naijiria n ṣiṣẹ takuntakun lati ri i pe eto aabo to nipọn wa kaakiri awọn ipinlẹ ni Naijiria.













