Aishat Lagos flood: Lẹ́yìn wákàtí 24 ní wọ́n rí òkú ọmọbìnrin náà tí àgbàrá òjò gbé lọ ní Suurulere

odo
Àkọlé àwòrán, Aishat dolooogbe ninu odo yii

Wón ti rí òkú ọmọbìnrin ti àgbàrá òjò gbé lọ ni Eko.

Awọn ẹbi ati ara ti sin arabinrin Aishat Mustapha ti agbara ojo gbe lọ ni Ọjọ Aje ni agbegbe Surulere ni ipinlẹ Eko.

Ninu atẹjade ti Ajọ pajawiri ni ipinlẹ Eko, LASEMA gbe lede ni wọn ti sọ wi pe lẹyin wakati mẹrinlelogun ni wọn ṣẹṣẹ ri oku arabinrin naa.

LASEMA ni arabinrin naa wa ni Kilasi SS3 ni ile iwe girama New Era, ni Surulere ni wọn si oku rẹ lẹyin ọjọ kan ni Canal Onilegogoro ni agbegbe Suurulere.

Awọn ara agbegbe naa ni wọn sin oku rẹ gẹgẹ bi ilana ẹsin Musulumi si ẹgbẹ Canal to wa ni agbegbe Onilegogoro, Rabiatu Thompson ni Surulere.

Canal
Àkọlé àwòrán, Ẹgbẹ Canal naa ni wọn sin oku ọmọ naa si ni ilana Islam

Iroyin fikun un wi pe ounjẹ ni iya Aishat n ta ni agbegbe Omololu ni Suurulure, ti baba rẹ si n ṣe oṣelu ni abẹle.

Ajọ LASEMA naa ṣalaye pe ojo arọọrọda naa wa lara afojusun ẹka to n risi ọrọ oju ọjọ ni Naijiria, NIMET to fi lede pe ojo to to 240 si 270 ni yoo rọ nipinlẹ Eko ti yoo si fa omiyale agbara ya sọọbu.

aishat
Àkọlé àwòrán, Won ti ri oku Aishat leyin wakati merinlelogun ti agbara ojo gbe e lo

Bakan naa ni wọn wa parọwa si awọn eniyan lati ri i wi pe wọn gbaradi fun ojo arọọrọda naa, ki gbogbo oju omi to wa layika wọn si mọ, ki omi le raaye lọ lai yawọ ile tabi sọọbu ni agbegbe wọn.

Wọn tun ni ki awọn eniyan ṣọra fun dida idọti si oju agbara

agbara ojo
Àkọlé àwòrán, Ojo arọọrọda lo fa ẹkun omiyale naa