EFCC: Ààrẹ Buhari ní gbogbo àwọn aṣèbàjẹ́ ni wọn yóò fojú winá òfin

Oríṣun àwòrán, Reuters
Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ni lọọtọ ni iwa ibajẹ ati jẹgudujẹra gbinlẹ ni orilẹede Naijiria.
Buhari sọ ọrọ yii lasiko ti oun fesi fun igba akọkọ lori bi wọn ṣe yọ Ibrahim Magu kuro ni ipo gẹgẹ bi adari Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹede Niajiria, EFCC.
Aarẹ ni gbogbo ọmọ Naijiria gbọdọ mọ wi pe wọn yoo jiyin ohun gbogbo ti wọn ba ṣe, paapaa awọn to di ipo mu lorilẹede Naijiria.
O ni bi ọwọ sinku awọn agbofinro ṣe mu Magu fihan pe ko si ẹni to kọja ofin ni Naijiria.
Aarẹ Buhari lasiko idibo sipo aarẹ ni ọdun 2015 ati 2019 sọ wi pe ọkan googi ninu ohun ti iṣejọba oun yoo ṣe ni gbigbogun ti iwa ibajẹ.
Amọ, awọn alatako ati onwoye ọrọ ilu n sọ wi pe aarẹ Buhari ko ṣiṣẹ takuntakun nipa gbigbogun ti iwa ibajẹ, nitori wọn fi ẹsun kan awọn to wa ni iṣejoba rẹ fun iwa ibajẹ.
- Gbajúgbajà òṣèré India, ọmọ, ìyàwó ọmọ àti ọmọ-ọmọ rẹ̀ lùgbàdì ààrùn Coronavirus
- Kí ló ṣẹlẹ̀ tí àwọn ọmọogun Nàìjíríà tó lé ní 350 fẹ́ kọ̀we fi iṣẹ́ sílẹ̀?
- 'Báyìí la ṣe rìn ín láti pápákọ̀ òfurufú Abuja sí Eko bí ìrìnà òfurufú abẹ́lé ṣe bẹ̀rẹ̀'
- Kí ló mú Obasanjo ti ilẹ̀kùn mọ́ ẹbí, òṣìṣẹ́, ojúlùmọ̀ ní ibi òkú àna rẹ̀?
N kò gba ₦4bn lọ́wọ́ Magu, ẹ má ró àjẹbánu mọ́ mi láṣọ - Osinbajo pariwo
Igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo ti sẹ lori ahesọ iroyin kan to ni Ibrahim Magu, alaga ajọ EFCC tẹlẹ, ti jẹwọ pe, oun tẹwọ gba miliọnu mẹrin naira lọwọ rẹ.
Atẹjade kan ti akọwe iroyin si igbakeji aarẹ, Laolu Akande fisita ni irọ to jinna sootọ ni awọn iroyin nipa isẹlẹ naa, to wa lawọn oju opo iroyin kan.

Oríṣun àwòrán, @YemiOsinbajo
Awọn iwe iroyin kan lo gbe iroyin naa jade pe, wọn fi ẹsun kan Ibrahim Magu pe, o ko owo to to biliọnu mọkandinlogoji naira jọ, to si fun Osinbajo ni biliọnu mẹrin naira ninu rẹ.
Ẹsun miran ti wọn tun fi kan igbakeji aarẹ ninu awọn iroyin naa ni pe, o pasẹ fun ajọ EFCC lati wọgile awọn ipinnu rẹ kan lai tẹle ofin to yẹ.
Amọ igbakeji aarẹ ti wa ni ofuutu fẹẹtẹ, aasa ti ko ni kaun ni awọn ẹsun naa, to si se apejuwe wọn bii ara ọna lati ta epo si asọ aala oun loju araye ni.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ibrahi Magu
Laolu Akande wa salaye pe, igbakeji aarẹ ni oun ko ni faaye gba irufẹ awọn iroyin eke yii lati si i oun lọna nidi sise isẹ ilu bo se yẹ.
Atẹjade kan to fi sita ni Osinbajo kede pe oun ti fa ọrọ yii le awọn agbofinro lọwọ fun iwadi ati igbẹjọ to yẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Bẹẹ ba gbagbe, Ibrahim Magu tii adele alaga fun ajọ EFCC fun ọdun marun, ni igbimọ kan ti aarẹ gbe kalẹ n tanna wadi rẹ lọwọ lori ẹsun iwa ajẹbanu ati aigbọran si awọn alasẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Àṣírí tú! Ẹ̀rọ ayàwòrán ara ọlọ́pàá fihàn pé ìgbà ogún ni George Floyd pariwo, kó tó kú
- Iléesẹ́ rẹ́kọ́ọ̀dù tí mo ti bẹ̀bẹ̀ láti kọrin, padà di tèmi lónìí - Ebenezer Obey
- Èyí kò wa pọ̀ jù, kí ló ń pa ọ̀pọ̀ dókítà ní Ondo báyìí?
- Ọ̀pá epo NNPC bú gbàmú ní Benin, òṣìṣẹ́ méje kàgbákò ikú òjijì
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ ní Ivory Coast, Olóòtú ìjọba, Amadou Gon Coulibaly jáde láye
- Tó o bá fẹ́ wọ bàálù lásìkò yìí, wo òfin tuntun tó tẹ̀lé
Àlàyé rèé lórí ìdí tí Magu àti awọn alága EFCC míràn ṣe bá ìtìjú kúrò nípò

Oríṣun àwòrán, Getty Images/others
Ọdun 2002 ni ijọba da ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ l'orilẹ-ede Naijiria, EFCC, silẹ.
Eyi si waye labẹ iṣakoso Aarẹ Olusegun Obasanjo.
Gẹgẹ bi ofin to da ajọ naa silẹ ṣe sọ, EFCC ni oju'se lati dena tabi wadii iwa ibajẹ.
O si tun ni ẹtọ lati gbe awọn afurasi lọ sile ẹjọ.
Lati ọdun 2003 ti ajọ EFCC ti bẹrẹ, Alaga mẹrin lo ti ni.
Awọn mẹrẹẹrin ni Mallam Nuhu Ribadu, Arabinrin Farida Waziri, Ọgbẹni Ibrahim Lamorde, ati Ibrahim Magu.
Sugbọn nkan ti a ṣakiyesi ni pe, gbogbo awọn alaga ajọ EFCC to ti jẹ, lo maa n koju awuyewuye kan, tabi omiran.
O le jẹ nigba ti eto iyansipo wọn bẹrẹ, ti wọn ba bẹrẹ isẹ, tabi ti wọn ba ti n ṣiṣẹ lọ.
Ẹsun to si wọpọ ti wọn fi ma n kan wọn ni aṣilo ipo, ati iwa ibajẹ.
Bi ọkọọkan wọn, isẹ ti wọn se ati bi wọn se ba itiju kuro lori aleefa se lọ ree:
Nuhu Ribadu (2003-2007): awọn 'ọta' aarẹ Obasanjo nikan lo n doju 'ija igbogun ti iwa ibajẹ kọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Aarẹ Oluṣegun Obasanjo lo yan Ribadu sipo gẹgẹ bi alaga akọkọ fun ajọ EFCC.
Obasanjo da a pada sipo lẹyin saa rẹ akọkọ, 'fun pe o ṣe daada".
Iṣejọba Aarẹ Umar Musa Yar'Adua lo yọ ọ nipo lẹyin ọsẹ diẹ to bẹrẹ saa keji gẹgẹ bi alaga EFCC.
Awọn ẹsun ti wọn fi kan Ribadu nigba naa ni pe, o lọwọ si fifi iya jẹ awọn afurasi ti ọwọ ajọ naa ba tẹ lọna to tako ẹtọ ọmọniyan.
Wọn tun fi ẹsun kan an pe, awọn 'ọta' aarẹ Obasanjo nikan lo n doju 'ija igbogun ti iwa ibajẹ kọ.
Lara ẹṣẹ ti ọpọ tun sọ pe Ribadu ṣẹ ni pe, ko sọ otitọ nipa iye dukia rẹ to kede.
Niṣe ni wọn rọ Ribadu loye kuro ni ipo Igbakeji Ọga agba ọlọpaa, si ipo kọmisana, ni kete ti wọn gba iṣẹ alaga ajọ EFCC lọwọ rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iyansipo rẹ ko ba ofin mu.
Lara awọn aṣeyọri rẹ ni bo ṣe mu Gomina ipinlẹ Delta nigba kan, James Ibori, to ji obitibiti owo ipinlẹ rẹ ko.
Ọrọ Ibori naa si ni ọpọ gbagbọ pe o fa yiyọ ti wọn yọ nipo alaga EFCC.
Farida Waziri (2008 - 2011): Wọn ni o yọnda awọn gomina tẹlẹ ti ajọ naa fi ẹsun ibajẹ kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ọdun 2011 ni Aarẹ Goodluck Jonathan, to yan Farida Waziri sipo alaga ajọ EFCC, gba iṣẹ lọwọ rẹ.
Lati ibẹrẹ iṣẹ rẹ ninu ajọ EFCC si ni awuyewuye ti n waye nipa rẹ.
Wọn fi ẹsun kan an pe, o ṣe oniduro fun gomina ipinlẹ Benue tẹlẹ, Gerorge Akume, ti EFCC fi ẹsun iwa ibajẹ kan labẹ iṣakoso Nuhu Ribadu.
Lara ẹsun ti wọn tun ka si Waziri l'ẹsẹ ni pe, o yọnda awọn gomina tẹlẹ ti ajọ naa fi ẹsun ibajẹ kan.
Jonathan sọ nigba naa pe oun yọ Waziri nipo "lati le mu atunṣe ba gbigbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria".
O ni oun pinnu lati gba iṣẹ naa lọwọ rẹ nitori ẹsun ati awuyewuye to n waye lori rẹ, lati ọdọ awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria, ati awujọ agbaye.
Ajọ keji to n gbogbun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, ICPC, sọ nigba naa pe oun n wadii Waziri fun iwa ibajẹ.
Igbakeji rẹ, Ibrahim Lamorde lo si gba ipo rẹ.
Ibrahim Lamorde (2011 - 2015): Wọn ni o kọ lati ko triliọnu meji aabọ si apo ijọba

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan Lamorde ni pe, o kọ lati ko owo to to triliọnu meji aabọ, ti ajọ naa gba lọwọ awọn olori to ji i ko, si apo ijọba.
Ṣugbọn Lamorde sọ fun BBC nigba naa pe, nitori pe ajọ EFCC n ṣe iwadii ọkunrin to fi ẹsun naa kan oun, lo ṣe ṣe bẹ ẹ.
Koda, ọpọ ọmọ Naijiria lo sọ nigba naa pe, ile aṣofin n fi oro ya oro lara Lamorde ni, fun bo ṣe n wadii awọn aṣofin kan.
Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan an pe o dari owo ti ajọ naa pa lara tita awọn dukia ti ijọba gba lọwọ Ọga Agba ọlọpaa nigba kan, Tafa Balogun, ati gomina ipinlẹ Bayelsa, Alamieyesiegha.
Ṣugbọn, Lamorde sọ pe oun ko jẹbi awọn ẹsun naa.
Ibrahim Magu (2015 - 2020): Wọn ni o n dari owo ti EFCC gba lọwọ awọn ọdaran si ibomii, o n ba oniwa ibajẹ ṣe pọ, o si ni afojudi

Oríṣun àwòrán, Others
Laarin awọn alaga mẹrin to ti dari ajọ EFCC, Ibrahim Magu lo koju awuyewuye julọ.
Ẹẹmeji ni ile aṣofin agba kọ lati buwọlu iyansipo rẹ, nitori iwe 'ẹ fura' ti awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ DSS kọ nipa rẹ.
Ipo adele alaga lo wa titi iyọnipo rẹ lọjọ Keje, oṣu Keje, ọdun 2020.
Pupọ ninu awọn ẹsun naa niroyin sọ pe, o wa lati ọdọ Agbẹjọro Agba fun Naijiria, Abubakar Malami, ati aabọ iwadii ti ajọ DSS fun ile aṣofin laarin ọdun 2016 si 2017.
Wọn tun fi ẹsun kan Magu pe, oun naa n dari owo ti EFCC gba lọwọ awọn ọdaran si ibomii, o n ba awọn oniwa ibajẹ ṣe pọ, ati afojudi si ọfiisi Agbẹjọro agba.
O farahan niwaju igbimọ tileeṣẹ aarẹ gbekalẹ lati ṣewadi ẹsun mẹrinlelogun ti wọn fi kan larin ọdun maarun to fi jẹ adele alaga ajọ EFCC.
Ṣugbọn ajọ EFCC tako iroyin to kọkọ jade sori ayelujara pe, Ibrahim Ibrahim Magu ti wa ni gbaga ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS.
Ajọ EFCC ṣalaye loju opo Facebook rẹ lọjọ Aje wi pe, lootọọ ni Magu lọ farahan niwaju igbimọ ijọba to ṣayẹwo iṣẹ EFCC lọjọ Aje niluu Abuja.
Ajọ naa fikun ọrọ rẹ pe, Ọgbẹni Magu gba ifiwepe lati ọdọ igbimọ naa nigba ti o n lọ si olu ileeṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ fun ipade kan.
- Bí Hushpuppi ṣe tiraka rèé l‘Eko, kí ọlà ‘òjijì’ tó dé
- Èèyàn 7 kú, 21 di àwátì lásìkò tí ọkọ̀ ojú omi dojúdé ní Eko àti Benue
- Ìjọba àpapọ̀ yóò ti afárá Third Mainland pa fún oṣù mẹ́fà láti ṣe àtúnṣe
- Akẹ́kọ̀ọ́ wọlé padà, ìjọba Oyo kò pèsè ìbòmú lòdì sí ìlérí rẹ̀
- Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ òṣèlú, ẹ̀sìn àti ẹ̀yà ṣe fa ogun abẹ́lé Biafra
- Kàkà k‘éwé àgbọn dẹ̀ lágbo òṣèlú l‘Ondo, akọ̀wé ìjọba tún kọ̀wé fipò sílẹ̀
EFCC ni ajọ DSS ko fi panpẹ ofin mu Magu, bẹẹ si ni igbimọ ijọba to lọ farahan niwaju rẹ ko fi tipa mu un pe ki o wa farahan.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Ẹwẹ, ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS naa ti sọ tẹlẹ irọ ni iroyin to tan kalẹ kaakiri pe, ajọ naa ti fi ọwọ ofin adele alaga ajọ EFCC, Ibrahim Magu.
Ninu atẹjade ti alukoro fun ajọ DSS, Ọmọwe Peter Afunanya fi sita lọjọ Aje, o ṣalaye pe iroyin ofege lawọn ileeṣẹ iroyin kan n gbe kiri lori ọrọ Magu

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ibrahim Magu
Ọmọwe Afunanya sọ pe ajọ DSS fi atẹjade sita nitori ọpọ lo n pe wọn, lati mọ bo ya lootọọ ni wọn ti fi panpẹ ofin mu Magu.
Ọpọ iwe iroyin papaa julọ lori ayelujara lo sọ pe, Magu ti wa ni gbaga DSS lori ẹsun pe o kojẹ ninu owo ti ajọ EFCC gba lọwọ awọn jẹgudujẹra ti wọn kowo Naijiria jẹ.
Koda awọn iwe iroyin kan tiẹ sọ pe awọn ẹṣọ Ọgbẹni Magu atawọn DSS fija pẹta nigba ti wọn fẹ mu un.
Ṣugbọn alukoro DSS ti sọ pe ayederu iroyin ni gbogbo ẹ.
"N24bn pọ̀ jù láti kọ́ ọ́fíìsì EFCC"
Ẹnu kò tí i sìn lára àjọ EFCC lórí iye tó lò láti kọ́ olú iléeṣẹ́ tuntun fún àjọ nàá.
Ilé tuntun ọ̀hún, ni alága àjọ nàá, tó n gbógun ti ìwà ìbàjẹ́ àti ìjẹkújẹ l'órílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ibrahim Magu ní '' ó yẹ kí àwọn ọmọ Nàìjíríà yin òun ni fún lílo bílíọ́nù mẹ́rìnlélógún Naira fi kọ́ ilé tó yẹ kí àwọn kọ́ pẹ̀lú ọgọ́rùn bílíọ́nù Naira.
Owó nàá pọ̀ kọjá bó ṣeyẹ láti fi kọ́ ìlé alájà mẹ́wàá
Ilé alájà mẹ́wàá ọ̀hún tó wà ní ìlú Abuja, ni ìrètí wà pé Ààrẹ Muhammadu Buhari yóò ṣí lọ́jọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Karùn ún.

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC
Àmọ́, Onímọ̀ kan nípa ìdíyelé ilẹ̀ àti ilé, tó bá BBC Yoruba sọ̀rọ̀ sọ pé "owó nàá pọ̀ kọjá bó ṣeyẹ láti fi kọ́ ìlé alájà mẹ́wàá nàá, tó fi mọ́ àwọn tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ó ní, ó ṣeéṣe kí àwọn irinṣẹ́ ètò ààbò tó jẹ́ ojúlówó wà níbẹ̀, tó fi mọ́ àwọn nkan mìi tí wọ́n kó síbẹ̀, ṣùgbọ́n kò yẹ kí iye tí wọ́n nàá láti fi kọ́ ìlé nàá tó bẹ́ẹ̀."
Láìpẹ́ yii, ni àjọ EFCC ké gbàjarè pé àìsí owó tótó n ṣe ìdíwọ́ fún iṣẹ́ òhun. Ìbéèrè tó ti wá gba orí ẹ̀rọ ayélujára ni pé, ṣé àjọ tí kò rówó ṣiṣẹ́ yẹ kó ná mílíọ́nù mẹ́rìndínlógún láti fi kọ́lè.

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC
Ìwé ìròyìn Premium Times jábọ̀ pé ''Magu fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé olú iléeṣẹ́ tuntun nàá kò le gba gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ àjọ nàá tó wà ní ìlú Abuja. Àti pé, wọn yóò ṣi maa lo olú iléeṣẹ́ àtijọ́ tó wà ní agbègbè Adetokunbọ Ademọla, ní ìlú Abuja.
Bákan náà, ó ni, "àwọn òṣìṣẹ́ àjọ nàá tó fi àwọn ilé tí wọn yá ṣe ọ́fíìsì nílùú Abuja, yóò ṣì maa lo àwọn ilé nàá."













