Ivory Coast: Lẹ́yìn ìpàdé aláṣẹ ìjọba ni wọn gbé lọ sílé ìwòsàn níbi tó kú sí

Amadou Gon Coulibaly

Oríṣun àwòrán, AFP

Inu ọfọ nla ni ijọba ati awọn eeyan orilẹede Ivory Coast wa bayii nitori iku ojiji to sadede mu olootu ijọba, Amadou Gon Coulibaly lọ.

Coulibaly, tii se ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni ẹgbẹ to n se ijọba lọwọ ni orilẹ naa ti fa kalẹ bii oludije ninu ibo aarẹ to n bọ losu kẹwa ọdun yii.

Igbesẹ naa lo si waye lẹyin ti aarẹ to wa nipo, Allassane Quatara ni oun ko ni lọ fun saa kẹta lori oye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Coulibaly si sẹsẹ ti ilẹ Faranse de ni, nibi to ti lọ setọju aisan ọkan to n baa finra fun odidi osu meji gbako.

Nigba to n sọrọ nipa ọfọ nla to ja lu orilẹede Ivory Coast yii, aarẹ Quattara ni lootọ ni ara Coulibaly ko ya lasiko ipade igbimọ alaṣẹ ijọba ti wọn se.

Ibi ipade yii si lo ni awọn ti tete gbe digba-digba lọ sile iwosan, sugbọn aisan lo se e wo, ko si ẹni to ri ti ọlọjọ se.

Amadou Gon Coulibaly

Oríṣun àwòrán, Others

"Mo n yonbo aburo mi, ọmọ mi, Amadou Gon Coulibaly, ẹni to ti jẹ alabasisẹ pọ mi fun ọgbọn ọdun gbako, ti mo si tun yin iranti akinkanju ọmọ ilẹ yii naa, fun atilẹyin tootọ rẹ, ifọkansin ati ifẹ si ilẹ baba rẹ."

Iku Coulibaly si ni yoo mu ki ominu wa lori eto idibo to n bọ lọna ni orilẹede naa.

Coulibalylo ti ni aisan ọkan lati ọdun 2012, to si ti lọ silu Paris lọjọ keji osu Karun fun isẹ abẹ.