Fayose: Ẹ yee ta dukia ti EFCC gba ni kọọrọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gomina Ayọdele Fayose ti ipinlẹ Ekiti ti ke si ijọba apapọ orilẹede Naijiria wipe asiko to lati kede iye awọn dukia ti ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu lorilẹede Naijiria, EFCC ti ri gba pada lọwọ awọn eniyan ti ọwọ ṣinkun ajọ naa ti ba lori ẹsun ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu.
Ninu ọrọ kan to fi sọwọ si ori ikanni ayelujara twitter rẹ lowurọ ọjọọbọ.
Gomina Fayose ni ohun to ku ti awọn ọms orilẹede Naijiria fẹ mọ bayii ni ẹkunrẹrẹ iroyin nipa awọn dukia ti ajọ EFCC ti gba dipo ariwo gee nitori gẹgẹbi o se sọ, 'pupọ awọn dukia yii ni wọn ti ta ti wọn ṣi tun ti tun ta.'
"Awọn ọmọ orilẹede Naijiria fẹ mọ iye dukia gan ti ajọ to n gbogun ti sise owo ilu basubasu lorilẹede Naijiria, EFCC ti gba pẹlu awọn eeyan to ra awọn dukia yii.
"Ta gan an lo pasẹ ki wọn ta awọn dukia wọnyii? Awọn ọmọ orilẹede Naijiria n fẹ ẹkunrẹrẹ iroyin nipa rẹ, kii se ariwo gee ni wọn n fẹ, nitori pupọ awọn dukia yii ni wọn ti ta, ti wọn si tun ti tun ta."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gomina ipinlẹ Ekiti wa gba ijọba apapọ orilẹede Naijiria lamọran lati gbe opo ayelujara kan kalẹ ti yoo wa fun kikede awọn dukia ti ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu lorilẹede Naijiria, EFCC ti gba lọwọ awọn to lu owo ilu ni ponpo ati awọn eeyan ti wọn ta awọn dukia naa fun.
Fayose to jẹ ọkan gboogi ninu awọn alatako aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari tun salaye siwaju sii wipe ko si bi awọn ọmọ orilẹede Naijiria yoo se ni igbagbọ to rinlẹ ninu ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu baṣubaṣu lorilẹede Naijiria, EFCC nigbati ajọ yii kan naa to sọ ni osu kẹrin ọdun 2016 wipe ifunrasi ti ko lẹsẹ n lẹ ni ẹsun iwa ibajẹ ti wọn fi kan alagaajọ to n se kokari ijihin dukia oṣiṣẹ ilu, CCT, Umar atipe yoo nira diẹ lati fidi rẹ mulẹ nile ẹjọ yoo ṣe tun wa yipada maa gbe arakunrin kan naa lọ siwaju ile ẹjọ nitori ẹsun yii.








