Ijọba ipinlẹ Ekiti f'ofin de Fayemi fun ọdun mẹwa

Ọmọwe Fayẹmi ni ere ọmọde ni igbesẹ ijọba fayose lati fofin de oun

Oríṣun àwòrán, Fayemi /twitter

Àkọlé àwòrán, Ọmọwe Fayẹmi ni ere ọmọde ni igbesẹ ijọba fayose lati fofin de oun

Ijọba ipinlẹ Ekiti ti f'ofin de minisita fun ohun alumọni ilẹ lorilẹede yii, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi fun ọdun mẹwa pe ko gbọdọ du ipo tabi di ipo oselu mu ni ipinlẹ naa.

Igbesẹ yi ko sẹyin abajade igbimọ oluwadi kan ti wọn gbe kalẹ lati tan ina wadi ẹsun sise owo ilu basubasu ti wọn fi kan Ọmọwe Fayẹmi, ẹni to figbakanri se gomina ipinlẹ Ekiti.

Iwe asẹ ijọba, (White paper) ti igbimọ isejọba ipinlẹ naa fi sita loti jẹyọ wipe ọmọwe Fayẹmi ko lẹtọ labẹ ofin lati du ipo kankan ni ipinlẹ naa fun ọdun mẹwa gbako.

Gomina Fayose

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government

Àkọlé àwòrán, Gomina Fayose

Asẹ yii ko mọ lori minisita ijọba apapọ naa nikan pẹlu bi wọn tun se fofin de ọgbẹni Dapọ Kọlawọle fun iye ọdun mẹwa kan naa.

Ijọba ipinlẹ Ekiti labẹ isejọba gomina Ayodele Fayose ti fẹsun kan gomina ana nipinlẹ Ekiti, Kayọde Fayẹmi pe laarin ọdun 2010 si 2014 to fi se ijọba, o se owo ijọba ipinlẹ naa basubasu eyi to sokunfa agbekalẹ igimọ oluwadi naa.

Gẹgẹbi iroyin to tẹ ileesẹ BBC lọwọ se salaye, abajade iwadi igbimọ naa lo sọọ yanya pe, Fayẹmi "ko yẹ ni ẹni ti o lee di ipo ilu mu ni ipinlẹ naa."

Gomina Fayose ati asiwaju rẹ nwaako

Oríṣun àwòrán, EKITI STATE GOVERNMENT

Àkọlé àwòrán, Gomina Fayose ati asiwaju rẹ nwaako

Igbimọ oluwadi naa ni Fayẹmi gbọdọ da owo to din diẹ ni biliọnu mẹta naira pada ninu owooya to jẹ biliọnu mẹẹdọgbọn naira ti wọn fi yanju isẹ agbase kan fun ọja igbalode kan nilu Ado Ekiti eleyi ti wọn kuna lati kọ lẹyin o rẹyin.

Bakanna ni gbimọ oluwadi naa tun gbee jade pe ki kọngila ti wọn gbe isẹ awọn aga ati isọna ileejọba tuntun ti Fayẹmi kọ gbọdọ da owo to le ni ọọdunrun miliọnu naira pada si asuwọn ijọba nitori owo isọ agbase naa ko yẹ ko ju ọrinlerugba miliọnu naira lọ.

Gomina Fayemi di minisita lẹyin to se gomina ọdun mẹrin nipinlẹ Ekiti

Oríṣun àwòrán, Kfayemi.com

Àkọlé àwòrán, Gomina Fayemi di minisita lẹyin to se gomina ọdun mẹrin nipinlẹ Ekiti

Awọn ẹsun jegudujẹra miran ti wọn tun fi kan minisita ọhun ni isẹ agbase ọkọ rira ti wọn gbe fun ileesẹ Cosharis, pẹlu awuyewuye lori owo isẹ eto ẹkọ kalekako, SUBEB to le ni ẹgbẹrin miliọnu naira eyi ti wọn pe ijọba Fayẹmi ya lọna ati le gba owo afikun ti ijọba apapọ lai yanju iwe ti wọn fi ya owo naa daradara.Nibayii, Ọmọwe Fayẹmi ti sapejuwe igbesẹ naa gẹgẹbi ere'mọde lasan.

Pẹlu ofin yi, Fayẹmi ko lee di ipo oselu mu fun ọdun mẹwa

Oríṣun àwòrán, Kfayemi.com

Àkọlé àwòrán, Pẹlu ofin yi, Fayẹmi ko lee di ipo oselu mu fun ọdun mẹwa

Ninu atẹjade kan ti ileesẹ alukoro minisita fun idagbasoke alumoni nilẹ Naijiria naa fi sita sọ gbangba pe erongba ijọba gomina Fayose nipa gbigbe igbimọ naa kalẹ ko ju lati ta epo si asẹ ala Ọmọwe Fayẹmi lọ

O ni iwe asẹ ijọba naa ko lee fopin si isẹ ilu ti gomina ana nipinlẹ Ekiti naa nse.

Fayẹmi ni igbesẹ naa ko ba ofin mu bẹẹ ni ko lẹsẹ nlẹ.