NNPC: Òpó ọ̀pá epo tí wọn ń rì lọ́wọ́ ló fa ìṣẹ̀lẹ̀ ìbúgbàmú náà

Oríṣun àwòrán, Others
Ile iṣẹ to n risi ọrọ epo rọbi ni Naijiria, NNPC ti salaye bi iṣẹlẹ to pa oṣiṣẹ meje ṣe waye ni agbegbe Gbetiokun, OML 40, in ilu Benin, ipinlẹ Edo.
Ninu atẹjade kan ti Adari eto Iroyin fun ileesẹ NNPC, Dokita Kennie Obateru fi sita lo ti salaye pe, isbugbamu ọpa epo naa waye lasiko ti wọn n ri opo ọpa epo mọlẹ.
Ajọ NNPC fikun pe, iwadii ni kikun ti bẹrẹ lori bi ibugbamu naa ṣe ṣẹlẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìtàn ayé Henry Fajemirokun, olówó tó fi owó mọ Olúwa àti ènìyàn
- Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ̀ ní Ivory Coast, Olóòtú ìjọba, Amadou Gon Coulibaly jáde láye
- Tó o bá fẹ́ wọ bàálù lásìkò yìí, wo òfin tuntun tó tẹ̀lé
- Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Oyo ti tẹ àwọn aṣekúpani tó ń ṣọṣẹ́ ní Akinyele
- Ìpínlẹ̀ Eko kéde ọ̀nà àbáyọ sí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ lásìkò àtúnṣe afárá Third Mainland
- Wo ìgbẹ́sẹ̀ méjọ tí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ gbọdọ̀ tẹ̀lé láti yọ igbákejì gómìnà
- Ilé aṣofin Ondo fọwọ́ òsì júwe ilé fún aṣòfin mẹ́ta pé wọ́n tàpá sí òfin ilé
Bakan naa ni wọn salaye pe, wọn ti gbe oku awọn eniyan naa lọ si ibudo igbokusi ni Sapele, ti wọn si ti fi isẹlẹ naa to awọn ẹbi ati ara wọn leti.
Ajọ NNPC ni, gbogbo awọn to wa ni ibi iṣẹlẹ naa ni awọn ti fi orukọ wọn sita, ti ko si si ẹni to sọnu.

Oríṣun àwòrán, NNPC
Ileesẹ elepo rọbi naa wa ba awọn ẹbi ati ara awọn to ku ninu isẹlẹ ibugbamu yii kẹdun, ti wọn si gbadura pe Ọ́lọ́run yoo fun wọn ni ẹmi lati la akoko iku ololufẹ wọn kọja lai lewu.
Ìjàmbá iná ọ̀pá epo tó wáyé l'Abule Egba kò leè fa ọ̀wọ́ngógó epo-NNPC

Oríṣun àwòrán, @trafficbutter
Saaju la ti fi to yin leti ni osu kejila lọdun 2018 pe, ajọ elepo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ijamba ina to ṣẹyọ ni ori ọpa epo rẹ kan lagbegbe abule ẹgba ni Eko.
Iṣẹlẹ ijamba ina naa sọ ni idaji ọjọru lori ọkan lara awọn ọpa epo ajọ naa kan ti awọn ọbayejẹ ti bajẹ.
Ọpọlọpọ mọto, ọja ati nkan amuludun lo jona ninu iṣẹlẹ ohun.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Oludari agba ajọ NNPC, Ọmọwe Maikanti Baru ninu atẹjade kan ṣalaye pe oun ti paṣẹ fun ọkan lara awọn ẹka ajọ naa to n ṣamojuto ọpa epo ati kiko epo pamọ, NPSC lati tete lọ tu iṣu de isalẹ ikoko ọrọ naa ki wọn lee mọ ohun to ṣokunfa ijamba ina naa.
Bakan naa lo ni iṣẹlẹ naa ko ni fa ọwọngogo epo ni agbegbe ipinlẹ Eko atawọn ipinlẹ to yii ka ati pe atunṣe yoo de ba ọpa epo ti o jona naa lẹyẹ-o-ṣọka.
Oludari ajọ NNPC naa ṣalaye pe ko si idi fun araalu lati ko aya soke lori boya ijamba ina naa yoo ṣokunfa ọwọngogo epo rọbi nitori, gẹgẹ bi Ọmọwe Baru ṣe sọ, ajọ NNPC ni epo bẹntiro atawọn ẹya epo miran ninu aka rẹ, eleyi ti yoo to orilẹede Naijiria lo fun ọjọ marundinlaadọta bi omiran ko ba tilẹ wọle.













