EFCC gbé ọmọ ilẹ̀ Britain sẹ́wọ̀n lórí ẹ̀sùn ìkówójẹ

Aworan ajọ EFCC ati ọmọ ilẹ Britain ti wọn fẹsun kan

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Ajọ to n ri si iwa jẹgudujẹra lawujọ lorilẹede Naijiria, EFCC ti fẹsun mẹrindinlogun kan awọn ọmọ ilẹ Britain meji kan to ni ṣe pẹlu kikowo jẹ.

Awọn alaṣẹ ajọ naa sọ pe James Richard Nolan ati Adam Quinn jẹ oludari ni ile iṣẹ Process and Industrial Developments (P&ID).

Ile iṣẹ naa gba ami ẹyẹ ara ọtọ kan ni ilodi si ijọba Naijiria latari akanṣe iṣẹ afẹfẹ gaasi kan to pa ile iṣẹ naa ati ijọba Naijiria pọ eyi to to iye owo dollar biliọnu mẹsan.

Agbẹjọro to n ṣoju Ọgbẹni Nolan ati Ọgbẹni Quinn ti pe ẹjọ kotẹmilọrun pe awọn ko jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an.

Bi o tilẹ jẹ pe Ọgbẹni Quinn wa loke okun ṣugbọn EFCC ti fi Ọgbẹni Nolan satimole titi di igba ti wọn yoo gba iwe beeli rẹ.

Ninu ọrọ ti wọn fi sita, ajọ EFCC ni ile iṣẹ P&ID kuna lati jabọ iye owo dollar marundinlaadoje sinu asuwọn owo tilẹ yii.

Bakan naa wọn fi ẹsun kan pe ile iṣẹ ko kede gbogbo iṣẹ ti wọn n ṣe fun ile iṣẹ to n ri si katakara lorilẹede Naijiria.

Eyi ni igbesẹ tuntun to n jẹyọ latara aawọ laarin awọn ile iṣẹ to jẹ ti ilẹ Britain nilẹ yii ati ijọba Naijiria lori òwò gaasi kan ti ko pari to ti waye latọdun 2010.

Ni ti ile iṣẹ P&ID, wọn ni ipa ti ijọba to yẹ ko tẹle rawọn lati pari iṣẹ naa lo fa ijakulẹ rẹpẹtẹ.

Ijọba Naijiria ni bi wọn ṣe ṣe akanṣe iṣẹ ọhun gan ti jẹ eyi ti yoo kuna ati pe ami ẹyẹ ti wọn gba gan kii ṣe ẹtọ to dara.

Àkọlé fídíò, Kengbe Ilorin: Àṣà ẹ̀yà Fulani, Bariba àti Gambari tó dàpọ̀ mọ́ ti Yoruba