Bukola Saraki: Ilẹ̀ tíléẹjọ́ gbẹ́sẹ̀lé ní Ikoyi tó eékà ilẹ̀ mẹ́rin

Ori ile Saraki
Àkọlé àwòrán, Ori ile naa

BBC Yoruba se abẹwo si ilẹ Sẹnatọ Bukọla Saraki to wa ni agbegbe Ikoyi nilu Eko eyi ti ileẹjọ gbẹsẹle.

Lasiko abẹwa ọhun, a se alabapade awọn oṣiṣẹ kan lori ilẹ naa, ti wọn si ṣalaye pe, iṣẹ oko ni Saraki fẹ maa ṣe lori ilẹ ọhun.

Ilẹ naa, ti o to eeka ilẹ mẹrin, lo wa ni ojule kẹtadinlogun, agbegbe MacDonald ni adugbo Ikoyi, ni ilu Eko.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Awọn agbaṣẹṣe meji naa ti ọkan n jẹ Bolt, ọmọ Ipinlẹ Bayelsa, ti ikeji si jẹ ọmọbibi ipinlẹ Edo ti o n jẹ Sunshine, sọ pe, awọn ko gbọ pe ile ẹjọ gbẹsẹ le ilẹ naa rara.

Aeoran adugbo ti ilẹ naa wa
Àkọlé àwòrán, Mí o gbà iwé ìpè kankan lóri idájọ yìí ooo- Bukola Saraki

Bukola Saraki figbe ta pé iléẹjọ́ ń fá orí òun lẹ́yìn òun

Ṣaaju asiko yii ni ilé ẹjọ́ gíga kan ní ìpínlẹ̀ Eko, tí gbẹ́sẹ̀ lé ilẹ̀ naa to jẹ ti gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ Kwara àti ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asofin àgbà nígbà kan rí, Bukola Saraki.

Ilẹ̀ ọ̀hun to wà ni ladugbo Ikoyi ni ipinlẹ Eko, ni adájọ àgbà Mohammed Liman pasẹ ki wọ́n gbẹ́sẹ̀ le, ki àwọn ajọ tó ń gbogun ti ìwà gẹ́gujdujẹra (EFCC) si fí iwé ìpẹjọ wọ́n sọwọ́.

Adugbo Ikoyi
Àkọlé àwòrán, Ile Olusola Saraki

Àjọ EFCC ní ilẹ̀ náà to wà nilẹ̀ lásàn ní Nọ17A òpópónà McDonald ní Ikoyi, ni àwọn fura si pé o jẹ èyí ti Saraki fi owó màgòmágò rà.

Nínú ìwé ẹ̀rí ti EFCC mú wá, ó fi hàn pé Saraki ṣe sáà meji gẹ́gẹ́ bí gómìnà ìpínlẹ̀ Kwara ní ọdun 2003 si 2011, ti o si gbà bílíọ̀nù méjìlá jade ní àpò aṣunwọn ipinlẹ Kwara to wa ni ile ifowopamọ kan.

Bákan náà lo san owo náà sinú àpò ìkówó pamọ tirẹ̀ ni ilé ìfówópamọ Access àti Zenith, sùgbọ́n olùrànlọ́wọ́ pàtàkì rẹ̀ kan Abdul Adama lo ba san owo náà lásìkò ọ̀tọ̀ọtọ̀.

Aare ile Igbimo Agba Ana

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Àkọlé àwòrán, Bukola Saraki

Agbẹjọ́rò EFCC ni ilé ẹjọ́ ni àsẹ láti gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ohun ini náà fún ìgbà díẹ̀, ti yóò si wà lábẹ́ àkóso ìjọba àpapọ̀.

Adájọ Liman wa dájọ pé, ki àjọ EFCC gbe jáde ninu iwe iroyin pé, wọ́n ti gbẹ́sẹ̀ le ilé náà, bákan náà lo fún Bukola Saraki àti ẹnikẹni tọ̀rọ̀ kan ni ọjọ́ mẹ́rìnlà, láti wá sọ ìdí ti ko fi yẹ ki wọn gbe ẹsẹ̀ le ilẹ̀ náà.

Ẹ̀wẹ́, Bukola Saraki ti fesi si àṣẹ̀ ilé ẹjọ pé, ìdájọ náà ni kọ́nu n kọ́họ ninu.

Gomina Ana ni Kwara

Oríṣun àwòrán, @bukolasaraki

Àkọlé àwòrán, Bukola Saraki

O ní o ṣeeṣe ko jẹ pe àjọ EFCC ti sí ilé ẹjọ́ lọ́nà lo ṣe ṣe irú ìdájọ bẹ́ẹ̀, àti pe, yálà oun tàbi agbẹjọrò oun kankan kò gbọ́ si ẹ̀sùn náà ki wọ́n to dájọ àti pé, ko si ìwé ìpè kankan si oun láti ọ̀dọ̀ àjọ EFCC.

Nínú àtẹjade kan ti olurànlọ́wọ́ rẹ lori igbohun sáfẹ́fẹ́ àti ìpolongo, Yusuf Olniyonu fisita sàlàyé pé, ilé ẹjọ gíga kan ni ilú Abuja naa ti dájọ lori ilẹ yìí, ti EFCC àti ilé iṣẹ́ to n ri si idájọ náà sì mọ̀ si.

Ilẹ Bukọla Asaraki

Olaniyonu fi kun pé, idajọ ilé ẹjọ́ giga ni pé ki àjọ EFCC fi ohun ini náà lọ́run sílẹ̀, titi ti ọ̀rọ̀ yóò fi pari.