Fayose: EFCC fi ẹ̀ṣùn olè jíjà àti àjẹbánu kan Fayose àti iléeṣẹ́ rẹ̀

Ayọdele Fayoṣe

Oríṣun àwòrán, @GovAyoFayose

Igbẹjọ Gomina Ipinlẹ Ekiti tẹlẹri, Ayodele Fayose fun ẹsun iwa ibajẹ ati lilu owo ilu ni ponpo ti bẹrẹ lọtun ni ilu Eko.

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ, EFCC ti pe awọn ẹlẹri rẹ lati wa sọrọ lori ẹsun lilu owo ilu to le ni biliọnu meji naira ni ponpo.

Ẹjọ naa to bẹrẹ ni ọdun kan sẹyin, ni wọn gbe kalẹ niwaju adajo C.J. Aneke ni Ile ẹjọ giga ni ipinlẹ Eko, lẹyin ti wọn gba ẹjọ naa lọ lọwọ Adajọ Mojisola Olatoregun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ẹsun onikoko mọkanla to nii se pẹlu ole jija, sise owo basubasu ni wọn fi kan Fayose ati ile isẹ rẹ, Spotless Limited.

Amọ, gomina tẹlẹri naa ni oun ko jẹbi ẹsun kankan ti wọn fi kan oun.