Kogi Crisis: Abaribe ní ìpìlẹ̀ Nàíjíríà ń mì pẹ̀lú ìwà ọ̀yájú sí ofìn ní Kogi

Oríṣun àwòrán, @EkeleHaruna
Adajọ agba nipinlẹ Kogi, Adajọ Nadir Ajana ti bura fun Edward Onoja gẹgẹ bii igbakeji gomina tuntun fun ipinlẹ Kogi.
Igbesẹ yii waye lẹyin ti ile asofin ti se ayẹwo tan fun igbakeji gomina tuntun naa.
Lasiko ayẹyẹ ibura naa, olori ile asofin ni Kogi, Matthew Kolawole sapejuwe iyansipo Onoja gẹgẹ bii ere jijẹ olootọ ati olufọkansin si gomina lasiko to fi jẹ olori awọn osisẹ lọọfisi gomina.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò fẹ́ ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ló mú mi máa wa ọkọ̀ taxi - Obìnrin tó ń wa Uber
- Iléẹjọ́ mú àdínkù bá owó onídùróó Sowore láti ₦100m sí ₦50m
- Ìgbésẹ̀ márùn-ún tí o lè gbé lati bọ́ láàyè lọ́wọ́ Ajinigbé
- Boko Haram ń kó ẹja gbígbẹ wọlé láti rí owó ra oúnjẹ - Iléeṣẹ́ ológun
- MTN Dáa padà, o kò gbọdọ̀ gba owó orí lọ́wọ́ oníbárà tó bá fi owó ránṣẹ́ - Ìjọba àpapọ̀
O wa rọ igbakeji gomina tuntun naa lati maa tubọ tẹle oju ọna otitọ ati isẹ asekara eyi to mu de ipo giga ọhun.

Oríṣun àwòrán, @EkeleHaruna
Ọjọ Ẹti to kọja ni ile asofin ipinlẹ Kogi yọ Simon Achuba gẹgẹ bii igbakeji gomina nipinlẹ naa lẹyin ti igbimọ oluwadi to tanna wadi rẹ jabọ pe ko ni ẹsẹ kankan lọrun.
Wayi o, olori ọmọ ẹgbẹ oselu to kere julọ nile asofin agba ilẹ wa, Senatọ Eyinnaya Abaribe ti kesi aarẹ Muhammadu Buhari lati dasi ọna to lodi sofin ti wọn gba yọ igbakeji gomina nipinlẹ Kogi.

Oríṣun àwòrán, @EkeleHaruna
Atẹjade kan ti Abaribe fisita nilu Abuja ni eyi ti jẹyọ pẹlu afikun pe, niwọn igba tijọba ipinlẹ Kogi ti kuna lati daabo bo ofin ilẹ wa, o yẹ ki aarẹ Buhari da si ọrọ naa lai fi ti ẹgbẹ oselu se.
- Èrò márùn-ún kú, méjì farapa, tí awakọ̀ sì fẹsẹ̀ fẹ nínú ìjàǹbá ọkọ̀ l‘Ondo
- Wo àwọn àkókò tó yẹ ko sàìsàn, tí ara rẹ yóò fì tètè dá
- Davido fi orúkọ bàbá rẹ̀, Adedeji, sọ ọmọ tuntun tó bí
- Oníbàárà tó bá fi owó ránṣẹ lórí ẹrọ ibaraẹnisọrọ yóò sanwo orí
- Ọdún mẹ́rin kò tó láti parí ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ní Ọ̀yọ́ - Seyi Makinde
Abaribe ni pẹlu iwa ọyaju tile asofin ipinlẹ Kogi hu si ofin ilẹ wa naa, a jẹ pe ipilẹ orilẹede Naijiria n mi ree.












