Revolution Now: Iléejọ́ tún wọ́gilé gbígbé ₦50m owó àsansílẹ̀ ààbò kalẹ̀

Ileejọ giga tijọba apapọ to wa nilu Abuja tun ti tun ero rẹ pa lori awọn gbedeke to gbe kalẹ lori gbigba oniduro asaaju ẹgbẹ ajijagbara Revolution Now, Ọmọyẹle Soworẹ.
Nigba to n kede ilana tuntun fun gbigba oniduro Soworẹ lasiko ijoko ile ẹjọ naa lọjọ Aje, Adajọ Ijeoma Ojukwu kede pe o nira fun oun lati gbagbọ pe iru eeyan to ni akọsilẹ nla bii Soworẹ yii ko ni ẹnikẹni ti yoo gbe ọgọrun milọnu naira kalẹ fun gbigba oniduro rẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- N kò fẹ́ ṣiṣẹ́ aṣẹ́wó ló mú mi máa wa ọkọ̀ taxi - Obìnrin tó ń wa Uber
- Boko Haram ń kó ẹja gbígbẹ wọlé láti rí owó ra oúnjẹ - Iléeṣẹ́ ológun
- Èrò márùn-ún kú, méjì farapa, tí awakọ̀ sì fẹsẹ̀ fẹ nínú ìjàǹbá ọkọ̀ l‘Ondo
- MTN Dáa padà, o kò gbọdọ̀ gba owó orí lọ́wọ́ oníbárà tó bá fi owó ránṣẹ́ - Ìjọba àpapọ̀
- Baṣọ̀run Gáà: Ó yan ọba mẹ́rin, tó sì pa ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àmọ́ ọba karùn-ún ló pa á
Bẹẹ ba gbagbe, ileẹjọ giga ijọba apapọ naa lo ti kọkọ kede gbigba oniduro Soworẹ pẹlu ọgọrun miliọnu naira ati oniduro meji ti wọn ni ilegbe ati ilẹ nilu Abuja.

Amọ lati bii osu kan sẹyin, tile ẹjọ naa ti gba oniduro Soworẹpklu awọn gbedeke to rọ mọọ, Soworẹ ti lee tẹle awọn ilana to rọ mọ gbigba oniduro rẹ naa, to si wa lahamọ titi di akoko yii.
Nibi ijoko ile ẹjs loni ni adajọ ti wa se adinku awọn gbedeke naa, to si kede pe ki wọn san aadọta miliọnu naira dipo ọgọrun miliọnu naira tile ẹjọ naa beere tẹlẹ.

Bakan naa nile ẹjọ tun kede pe oun ti wọgile aadọta miliọnu naira owo asẹsilẹ fun aabo ti oun n beere lọwọ Soworẹ, kiwọn to lee gba oniduro rẹ.
Lori akọroyin ti wọn jọ mu oun ati Soworẹ si ahamọ lọjọ kannaa, Adajọ tun se adinku ilana gbigba oniduro tiẹ naa, lati aadọta miliọnu naira si ogun miliọnu naira.








