Ọ̀fẹ́ ni 'Bail': Ajulo ní ó lòdì sófin láti sanwóo béèlì fáwọn ọlọ́pàá, ẹ sọ́ra!

Shehu Lawal

Oríṣun àwòrán, Others

Àkọlé àwòrán, Igbakejì Ọ̀gá Àgbà Ọlópàá ní ìlú Eko, Lawal Shehu ti kìlọ̀ fún àwọn ọlọ̀paa lati sọra fun gbigba beeli lọwọ awọn ti wọ́n fẹ̀sun kan.

Agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan, Kayode Ajulo ti ni awọn ọdaran lo ma n san owo beeli fun ọlọpaa, ẹnikẹni ti o ba si lee fi ogun rẹ gbari pe oun ko dẹsẹ, ko yẹ ko sanwo kankan.

Ajulọ sọ ọrọ yii lasiko to n fesi si ọrọ ti Igbakeji Ọga Agba ọlọpaa ni ilu Eko, Lawal Shehu sọ, eyi to fi n kilọ fun awọn ọlọpaa, pe ki wọn sọra fun gbigba owo fun beeli lọwọ awọn ti wọn fẹsun kan.

O salaye pe, gbigba beeli afurasi tumọ si pe eeyan kan wa gba oniduro ẹni ti wọn fẹsun kan, ti yoo si jẹjẹ pe afurasi naa ko ni salọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bakan naa lo ni beeli gbigba wa fun awọn eniyan ti wọn wa lahamọ agọ ọlọpaa, amọ ti wọn n beere fun itusilẹ lati lọ si ile pẹlu oniduro, lai ti foju ba ile ẹjọ.

Ọlọpaa to gbe akọle lọwọ pe ọfẹ ni gbigba beeli afurasi

Oríṣun àwòrán, @PoliceNG

Agbẹjọrọ naa ni ẹni ti ko ba daran lasẹ lati beere fun beeli lai san eepinni, pẹlu afikun pe ọmọ Naijiria lẹtọ lati fi ẹjọ ọlọpaa sun, ti wọn ba gba owo fun beeli lọwọ wọn.

Kayode Ajulọ fikun wi pe, o seese ki ẹni ti ile ejọ ko ti dajọ fun lati lọ si ẹwọn, beere beeli pe ki wọn fi oun silẹ ki oun lo sile.

Agbẹjọro ati ajafẹtọ ọmọniyan naa ni ki awọn ọmọ Naijiria mase duro, ki ọlọpaa gbe wọn lọ sile ẹjọ, ki wọn to beere fun beeli.