EFCC: Ọwọ́ pálábá àwọn ọmọ China méjì tó fẹ́ fún ọ̀gá EFCC ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ N100m ségi

Awọn ọmọ ilẹ China

Oríṣun àwòrán, Faceboo/EFCC

Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lorileede Naijira EFCC ti sọ iwọ sodo ti o si ti mu ẹja nla pẹlu awọn ọmọ ilẹ China meji kan to gbiyanju lati fun ọga ajọ naa kan ni ọgọrun miliọnu Naira lowo abẹtẹlẹ.

Eka ileesẹ naa to wa ni Sokoto ni o gba awọn mejeeji yi mu ti wọn si ti safihan owo naa ati awọn afunrasi yi loju opo Facebook ajọ EFCC.

Ninu ohun ta ri ka nibẹ, Ọgbẹni Meng Wei Kun ati Xu Koi fẹ fun ọga EFCC agbegbe Sokoto ni owo abẹtẹlẹ aadọta miliọnu naira ti wọn ko wa ba eleyi to jẹ idaji ọgọrun miliọnu ti wọn fẹ fun ki o ba le mẹnumọ lori iwaadi kan tajọ naa n se lori ileesẹ wọn.

EFCC sọ pe awọn n se iwaadi aṣemaṣe ti awọn fura si pe ileesẹ Zhonghao Nig. Ltd tawọn arakunrin naa n ba sisẹ mọ nipa rẹ.

Ko sẹyin isẹ agbaṣe oni aadọta biliọnu naira ti ijọba ipinlẹ Zamfara gbe fun wọn laarin ọdun 2012 si 2019.

Ninu isẹ ti EFCC n tọ pinpin yii la ti ri isẹ agbaṣẹ oju ọna laarin ilu bi ti Gummi, Bukkuyun, Anka ati Nassarawa to fi mọ isẹ agbaṣe gbigbẹ ẹrọ kanga igbalode(borehole) mejidinlaadọsan ni ijọba ibilẹ mẹrinla ni ipinlẹ naa.

A tun ri ka ninu atẹjade ti EFCC fi sita pe nigba tawọn ọmọ ilẹ China yii ri pe awọn oṣiṣẹ ajọ naa ko jawọ ninu iwaadi wọn, ni wọn ba nawọ aba lati fun wọn ni abẹtẹlẹ ọgọrun miliọnu naira ki wọn ba le gbagbe ọrọ naa.

EFCC lawọn ṣebi ẹni gba lati juwọ silẹ ni wọn ba fi gbe idaji owo naa wa ti wọn si ṣeleri lati mu iyoku wa ti ọrọ ba yanju.

Awọn aṣoju ileeṣẹ naa meji Meng Wei Kun ati Xu Kuoi ni wọn fi paali gbe owo naa wa si ileeṣẹ EFCC to wa ni opopona papakọ-ofurufu ni Sokoto.

Lana tii ṣe ọjọ kọkanla oṣu Kaarun ni ọwọ tẹ wọn.

Ọwọ́ EFCC tẹ ọ̀kan lára àwọn ti FBI fi èsún jìbìtì kàn!

EFCC sọ pé wọ́n ti fi pańpẹ́ ọba mú ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógójì afurasi oní jìbìtì kan ní ìlú Ilọrin.

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ lorilẹ-ede Naijiria, EFCC ti sọ wi pe, wọn ti fi panpẹ ọba mu Oyediran Joseph.

O jẹ ọmọ ọdun mẹrindinlogoji ati ọkan lara awọn ti ajọ FBI fesun kan pe o lu jibiti.

Oyediran Joseph

Oríṣun àwòrán, @officialEFCC

Ọga agba fun ajọ EFCC ni Ilọrin, Isyaku Sharu, ti o soju alaga fidihẹ fun ajọ naa, Ibrahim Magu, lo fi ọrọ naa lede nibi ifọrọwerọ pẹlu awọn oniroyin nilu Ilọrin.

Magu wi pe, Ajọ EFCC ti ni ifọwọ sowọpọ pẹlu ajọ ọtelẹmuyẹ ilẹ Amẹrika, FBI, lati foju awọn afurasi naa lede.

O ni "Ni osẹ meta sẹyin ni orilẹ-ede Amẹrika kọwe siwa lati ranwọn lọwọ lọna lati mu awọn afurasi oni jibiti.

Iwadii ti a ṣe fi yewa pe, Joseph yi ti jẹ anfani owo jibiti, ti oye rẹ to ọgọta milliọnu naira, ti wón fi ranṣẹ lati ori ẹrọ ifoworanṣẹ Western Union."

Bi ẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni ajọ FBI fi orukọ ọgọrin eniyan lede ti wón fi ẹsun kan wi pe, wọn ṣe gbajuẹ nilẹ Amẹrika, ti ọpọlọpọ wọn jẹ ọmọ Naijiria.

Ibaṣepọ to wa laarin ajọ EFCC ati FBI ni Magu sọ pe o ti n so eso rere bayii.