Seyi Makinde: Ìyàtọ̀ yóò dé bá àwọn òṣìṣẹ́ lásìkò yìí

Oríṣun àwòrán, Google
Gomina Ipinlẹ Ọyo, Seyi Makinde ti ni ẹgbẹrun lọna aadọtalelẹgbẹta Naira (N650,000) ni oun n gba gẹgẹ bi owo oṣu lati igba ti oun ti bẹrẹ iṣejọba gẹgẹ bi gomina.
Makinde sọ eyi lasiko to n sọrọ lori mimu imugbooro ba igbe aye awọn oṣiṣẹ ijọba ni ipinlẹ naa.
O ni iyatọ yo de ba awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ naa lasiko ti oun bura wọle fun awọn kọmiṣọnna tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan ni ipinlẹ naa.
Gomina ipinlẹ Ọyọ naa fikun un wi pe idi ti oun fi jẹ ki awọn eniyan mọ iye owo ti oun gba gẹgẹ bi owo oṣu ni lati mu ileri ti oun ṣe wi pe awọn eniyan yoo ma a mọ bi oun ṣe n na owo ijọba ipinlẹ naa.









