Amẹrika dá akẹ́kọ́ọ̀ Harvard pada sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ nítori ǹkan ọ̀rẹ́ rẹ̀ kọ lóri ayálujára

Awọn ọmọ ilé iwé ń lọ ilé iwe

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Amẹrika dá akẹ́kọ́ọ̀ Harvard pada sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ nítori ǹkan tó kọ lóri ayélujára

Àwọn aláṣẹ ilẹ̀ Amẹríka tí lé ẹni ọdún mẹ́tàdílógun kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà wọlé sí ilé ẹkọ́ fásìtì Harvard pada sí orilẹ̀ -èdè rẹ̀ nítori ọ̀rọ̀ kan ti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kọ sorí ẹ̀rọ́ ayelujara Facebook.

Ismail Ajjawi tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà wọlé fún ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ sí Harvard, sùgbọ́n àwọn aláṣẹ US kọ̀ láti jẹ́ kó wọ ìlú láti pápákọ̀ ofurufu ni wọ́n ti dáa pada.

Ismail tó jẹ́ ọmọ Palestine sùgbọ́n to n gbé Lẹbanon, sọ pé àwọn aláṣẹ US bere àwọn ibeere lórísírisi lọ́wọ́ oun ni pápákọ̀ ofurufu Boston lọ́ja Jimọ.

O ní wọ́n wọ́gile ìwé ìrìnà Visa òun lẹ́yìn ti wọn wo ẹrọ iléwọ àtí kọmputa alágbéletan rẹ̀.

Bí Ismail ṣe ja fitafita tó pé oun kò ni ǹkan ṣe pẹ̀lú ohun ti wọ́n ri lóri fọọnu oun tó àti pé ọ̀rk oun ló kọ síbẹ̀ àwọn ọlọpàá aṣọbode ní àwọn kò le gbà ki o wọle si ilẹ̀ Amẹrika.

Iwé ìròyìn Washington Post sàlàyé pé Ismail sọ̀rọ̀ lóri àtẹjáde kan.

"Ọkan nínú àwọn òṣìṣẹ́ tó tó n ri sí ìjáde àti iwolé lorilẹ̀-èdè Amerika sọ pé òun ri èròngba ẹnikan lóri Facebook rẹ̀ tó n sọrọ òṣèlú lòdi si ìjọba orilẹ̀ èdè Amérika"

"Mo sọ fún wọ́n pé mí o ni ǹkankan ṣe pẹ̀lú àwọn èròngba náà, bákan náà ni mí o si gbé ìgbéṣẹ kankan lóri ǹkan ti ó kọ, mo sàlàyé pé kò yẹ ki wan múmi fún ẹ̀ṣẹ̀ ti mí o mọ nípa rẹ̀"

Agbẹnusọ Aṣobode àti alábo ilẹ̀ Amerika (CBP) Michael McCarthy sàlàyé pé àwọn gbe ìgbésẹ̀ náà látàri àwọn ǹkan tí àwọn ti ṣe àwári lásìkò tí wọ́n ń ṣe àyẹwò (CBP)

Harvard

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, Harvard University say dem dey try to settle di mata before class go begin

McCarthy kò sàlàyé jù báyìí lọ nítori pé ṣe ǹkan tí àwọn gbọdọ máà fi gbogbo ẹni sọ.

Ismail ti wọn gbà wle fun ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ tí pada si Lebanon.

Ilé iwé Harvard náà ti sọ pé àwọn ń ba àwọn ẹbí ọmọ náà sọ̀rọ̀ àti pé àwọn ń gbìyànju láti pẹ̀tù sááwọ náà kí ìdánilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ ni ọjọ́ kẹta oṣù kẹsàn

Ajọ kan ti kìí ṣe ti ìjọba tí pèsè ìrànwọ láti gbẹjọ rò fún Ismail.

Nínú Oṣù keje, ilẹ Amẹrika ti ní gbogbo ẹni tó ba ń fẹ́ láti gba iwé ìrìnà ilẹ̀ Amẹrika gbọ̀dọ̀ sàfihan àwọn ojú opó ayélujara wọn, èyí jẹ́ ọkan pàtàkì lárá òfin tuntun ti wọ́n yàn

Wọn fi kún pé arinrin ajo yóò mú orukọ to n lọ loju opo ayelujara rẹ̀ kalẹ̀, pelu gbogb atẹjisẹ tó ti gbà láti ọdún márun ṣẹyin àti nọmba foonu wọ́n