Spaghetti, milíìkì, Chivita àti Àǹkàrá sọ Rabiu dèrò ẹ̀wọn ni Eko

Oríṣun àwòrán, @others
Adajọ ni ki Kabiru lọ kọ ẹkọ iwa ootọ sii nile ikọni lẹkọ ọmọluwabi tijọba.
Ileejọ Magistrate ti Ikẹja nipinlẹ Eko ti dajọ ọdun meji latimọle fun ọdọmọkunrin Kabir Rabiu.
Kabir Rabiu to jẹ ọmọ ogun ọdun ni o ni oun jẹbi ẹsun ole ti wọn fi kan oun ati pe iṣẹ eṣu ni.
DSP Ezekiel Ayorinde lo fi ẹsun kan Rabiu pe O ji Spaghett kan, maltina alagolo kan, ẹlẹrindodo Chivita meji, yogọọti agolo dudu kan, ọra ọṣẹ ifọṣọ Ariel kan ati ankara marun un.
Odiwọn iye owo gbogbo nkan to ji jẹ ẹgbẹrun mejidinlogun o le ni irinwo ati ọgbọn naira (18, 430 naira).
Wọn ni Rabiu ji awọn nkan wọnyii nile itaja kan ni agbegbe Abule Egba lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹjọ ọdun yii.
Rabiu ti ko ri adirẹẹsi ile to n gbe fi silẹ nitori o ni ibi ti ilẹ ba ṣu si naa ni ile bẹbẹ pe ki adajó foju aanu wo oun.
Lẹyin igbẹjọ naa lọjọru ni Adajọ Osunsanmi ni ki Rabiu lọ lo ọdun meji nile ikọni niwa ọmọluwabi ti ijọba to wa ni agbegeb Adigbẹ nilu Abẹokuta to jẹ olu ilu ipinlẹ Ogun.
DSP Ezekiẹli ni ọja naa jẹ ti ọgbẹni Mohammed Muraina to n ta worobo ati atẹ ninu ṣọọbu rẹ ni Abule Ẹgba.
O ni wọn ti gba awọn ẹru naa pada lọwọ Kabir Rabiu lẹyin ti ọwọ ofin tẹẹ.
Iwa ole jija Kabir yii tako ofin ipinlẹ Eko ti abala 287 tọdun 2015.












