FBI List: Ìwádìí EFCC àti FBI ti ń so èso rere

Oríṣun àwòrán, @ChikeEjiofor
Alaga fidihẹ fun ajọ EFCC, Ibrahim Magu, ti sọ wi pe, ajọ naa ti bẹrẹ si nii ṣe akojọpọ iwadii awọn ọmọ Naijiria ti ajọ ọtẹlẹmuye Amẹrika, FBI, fi ẹsun kan lori iwa jibiti.
Ẹni ti o ṣoju Magu nibi ifọrọwerọ kan pẹlu awọn oniroyin, Friday Ebelo, lọ sọ ọrọ yi nilu Ibadan.
O salaye pe, iwadii ti ajọ EFCC n ṣe jẹ ọkan lara ibaṣepọ ti o wa laarin ajọ EFCC ati FBI, lati foju awọn afurasi naa lede.

Oríṣun àwòrán, @FBI
Friday salaye sii pe, iwadii ti wọn n ni lati mọ ibaṣepọ to wa laarin awọn afurasi ni orilẹ-ede yi ati awọn ojugba wọn to wa loke okun.
Bakan naa ni o tesiwaju pe, lara awọn iwadii ti ajọ naa ti ṣe ti ranwọn lọwọ lati fi panpẹ ọba mu ọpọlọpọ awọn afurasi.
- 'Ambode ṣì gbọdọ̀ yọjú sí wa - Ilé aṣòfin Eko'
- Ìpàdé àpérò kọ́ ló kàn, àdánìkànjẹ ẹ̀yà kan ni ká dẹ́kun ní Nàíjíríà - Òǹwòye
- "Bi mo tilẹ̀ jẹ́ apárí síbẹ̀ kò tìmí lójú", ọ̀pọ̀ dẹ́yẹ sí mi nítori mó ni ààrún ori pípa- Liliya Kukushkina
- A ṣetán láti ran àjọ aláàbò alájùmọ̀ṣe lọwọ fún ààbò tó péye nílẹ Yorùbá - Ọlọ́pàá Ogun
O wa fi kun un pe, lara awọn ti àwọn ti ri mu ni Ajayi Gbenga Festus, ẹni ti ọwọ ajọ na tẹ nilu Ado-Ekiti.
Bi ẹ o ba gbagbe, awọn afurasi ọgọrin, ti ọpọlọpọ wọn jẹ ọmọ Naijiria ni ajọ FBI ti fi ẹsun kan wi pe, wọn lu gbajuẹ nilẹ Amẹrika.








