Daniel Lewis Lee, ẹni àkọ́kọ́ tí wọ́n yóò yẹgi fún ní US lẹ́yìn ìdádúró ọdún 17

Daniel Lewis

Oríṣun àwòrán, AFP

Fun igba akọkọ lati ọdun mẹtadinlogun, orilẹ-ede America yoo yẹgi fun awọn ọ̀daràn kan ni Indiana lọjọ Aje.

Eyi ri bẹẹ lẹyin ti ile ẹjọ kotẹmilọrun kan fi àṣẹ sii.

Ijọba fi ẹsun kan Daniel Lewis, ati isọngbe rẹ kan, pe wọn pa eeyan mẹta ninu ìdílé kan naa lọdun 1996.

Nise lo pa tọkọtaya ati ọmọ wọn kan, to si ju oku wọn sinu odò adágún kan.

Àmọ́, diẹ lara mọlẹbi wọn tako idajọ iku naa, ti wọn si fẹ ki wọn da a duro na, nitori kikopa nibẹ le fi wọn sinu ewu coronavirus.

Ṣugbọn nkan ti idajọ naa tumọ si nipe ijọba le tẹsiwaju lati fa abẹrẹ olóró si ara àwọn ọ̀daràn naa lati sekupa wọn.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun lo yi idajọ ile ẹjọ kekere to da pipa Lee duro, danu.

Ile ẹjọ kotẹmilọrun naa sọ pe ko si ofin to faaye gba ẹbí awọn ti wọn pa láti wa nibi ti wọn yoo ti pa awọn ọ̀daràn naa, ati pe awijare ẹbí naa ko fẹṣẹ mulẹ ninu ofin.

Ṣugbọn o, awọn ẹbi tun le pe ẹjọ kotẹmilọrun si ile ẹjọ to gaju lọ, lati da pipa awọn ọ̀daràn naa duro, ti wọn ba le ṣe bẹẹ ki o to di aago mẹrin irọlẹ.

Oṣu Kejila lo yẹ ki wọn o yẹgi fun Lee, ẹni ọdun mẹtadinlaadọta, ṣugbọn wọn da a duro lẹyin ti ile ẹjọ pagidina idajọ iku ti wọn da fun.

Earlene Peterson, ẹni ọdun mọkanlelọgọrin, ti wọn pa ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ-ọmọ rẹ, ati ọkọ ọmọ rẹ, lo tako idajọ iku naa.

O ni ẹ̀wọ̀n gbere ni oun n fẹ ki wọn o ju Lee ati ẹnikeji rẹ si i.

Iya àgbà naa sọ ninu fidio kan lọdun to kọja pe "Lootọ ni Daniel ba aye mi jẹ, sugbọn mi o gbagbọ pe gbigba ẹ̀mí rẹ yoo mu ayipada ba mi".

Ki lo mu ki ilẹ America o ṣe ayipada si idajọ ikú?

Isejọba Aarẹ Trump lo sọ lọdun to kọja pe oun yoo bẹrẹ idajọ iku pada lẹyin idaduro ọlọjọ pipẹ.

Àkọlé fídíò, Ọmọ ọdún méjìlá yìí sọ bó ṣe di téélọ̀ táwọn àgbà ń bẹ́rí fún

Sugbọn awọn kan tako o pe, igbesẹ oṣelu ni, ti wọn si tun sọ pe igbesẹ naa yoo mu ki wọn o ma a fi ikanju ṣe igbẹjọ.

Louis Jones Jr, ẹni ọdun mẹtalelaadọta ni ijọba apapọ ilẹ America pa gbẹhin, fun pe o pa sójà kan to jẹ ẹni ọdun mọkandinlogun, Tracie Joy McBride.

Ọdun 1972 ni ile ẹjọ to gaju lọ l'America fofin de idajọ iku, to si wọgile awọn idajọ iku to wa nilẹ lasiko naa.

Sugbọn nigba to di ọdun 1976, ile ẹjọ yii kan naa lo tun pada fi aaye gba àwọn ijọba ipinlẹ lati maa ṣe idajọ iku.

Ijọba lo sọ ọ di òfin lọdun 1988 pe ki ijọba apapọ naa o bẹrẹ rẹ pada.

Orilẹ-ede America nikan kọ ni wọn ti maa n ṣe idajọ iku fun awọn ọ̀daràn.

O wọpọ ni awọn orilẹ-ede bi Naijiria, Saudi Arabia, ati awọn miran nilẹ Asia ati kaakiri agbaye.