Amotekun: Àwọn ọdẹ nìkan kọ́ ni àmọ̀tẹ́kùn wà fún, a gba àwọn ọ̀dọ́ tó sán eegun pẹ̀lú

Oríṣun àwòrán, others
Oludari fun ikọ Amotekun nipinlẹ Oyo, Ajagunfẹyinti Olayinka Olayanju tun ti fi idi rẹ mulẹ pe o di dandan kawọn eeyan to ba fẹ dara pọ mọ ikọ Amotekun fi orukọ silẹ lori ayelujara.
Olayanju fi idi ọrọ naa mulẹ lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, eyi to fi n fesi lori bi awọn ọdẹ ibilẹ to fẹ kopa ninu ikọ Amotekun ṣe tako igbesẹ fifi orukọ silẹ lori ayelujara.
Olayanju ni ko si ohun to nira ninu fifi orukọ silẹ lori ayelujara nitori ko si ibudo itakun agbaye ti wọn ba lọ lati fi orúkọ silẹ, ti wọn ko ni seranwọ lati ba wọn ṣe.
"Fọọmu Amotekun naa ko le rara lati ṣe. Ohun ti wọn n beere ni orukọ wọn, adugbo, ẹkun idibo wọn, iriri nipa sise aabo ilu, ẹgbẹ ọlọdẹ ti wọn wa ati Baalẹ wọn."
Bakan naa ni oludari ikọ Amotekun nipinlẹ Oyo fikun pe awọn to ba fi orukọ silẹ yoo mu fọọmu naa tọ Baalẹ ati asofin to wa lati ẹkun idibo wọn lọ, ti awọn mejeeji yoo si buwọlu u.
Nigba to tun n sọ nipa ọpọ anfaani to wa nidi ki awọn osisẹ Amotekun fi orukọ silẹ lori ayelujara, Olayanju ni o see ṣe ki igbanisisẹ wọn fi sinu ẹgbẹ kan ju ọkan lọ laarin ẹgbẹ ọlọdẹ, onimọto, agbẹkọya ati OPC.
Yatọ si eyi, o ni fifi orukọ silẹ lori ayelujara ko ni jẹ ki wọn fi igba kan bo ọkan ninu nigba eto igbanisisẹ naa nitori awọn eeyan to fi ara wọn jin si iṣẹ ilu lo fẹ ṣe Amotekun.
Ajagunfẹyinti Olayanju tun sisọ loju rẹ pe awọn osisẹ Amotekun ko lee jẹ puruntu nikan nitori wọn gbọdọ mọ nnkan kọ tabi ka lati fi lo awọn ẹrọ igbalode kan feto aabo.
"Bi osisẹ Amotekun ko ba mọọkọ tabi mọọka, bawo la ṣe fẹ ṣe idanilekọọ fun wọn, bawo ni yoo ṣe kọ akọsilẹ nipa awọn iṣẹlẹ to ba waye ati ẹri to ni? Kii kuku ṣe pe a fi ṣe ti puruntu nikan amọ yoo jẹ amulumọla ọdọ to le kọ tabi lagbara ati puruntu.
Olayanju ni kii ṣe ipinlẹ Oyo nikan ni eyi ti n waye sugbọn ilana igbanisisẹ kan ṣoṣo ni gbogbo ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba n lo.













