Coronavirus in Nigeria: Nítorí COVID-19, ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara kó ọ̀dọ́ 50 tó lọ sí ilé ijó sí gbaga

Ilu Ilorin

Oríṣun àwòrán, Bhenji

Àkọlé àwòrán, Nítorí COVID-19, ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara kó ọ̀dọ́ 50 tó lọ sí ilé ijó sí gbaga

Aadọta awọn ọdọ ti ọjọ ori wọn ko ju ogun ọdun si ọgbọn ọdun lọ lọwọ ofin tẹ lowurọ ọjọ Abamẹta nile ijo kan nilu Ilọrin

Igbimọ amusẹya lori ajakalẹ arun COVID-19 ni ipinlẹ Kwara lo ko wọn si gbaga.

Igbimọ naa ni wọn tapa si ofin to de ile ijo lasiko COVID-19 yii ni

Atẹjade kan ti igbimọ naa fi sita, eyi ti agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Kwara fi ọwọ si lo yọju ọrọ yii sita.

Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ awọn eeyan kan lo sin igbimọ to n ṣe kokaari eto igbogun ti ajakalẹ arun coronavirus ni ipinlẹ naa ni gbẹrẹ ipakọ.

Ilu Ilorin

Oríṣun àwòrán, Bhenji

Àkọlé àwòrán, Nítorí COVID-19, ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara kó ọ̀dọ́ 50 tó lọ sí ilé ijó sí gbaga

Eyi lo jẹ ki igbakeji gomina nibẹ fi ọwọ ofin ko awọn awọn ọmọ igbimọ naa sodi lọ sileejo naa.

Dokita Ọladiji to jẹ alaga igbimọ igbaninimọran lori arun naa sọ pe o ṣeeṣe ki wọn ran gbe awọn ọdọ naa lọ sile ẹjọ fun titapa si ofin to wa nilẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ ṣi tabi lọ si ile ijo lasiko yii.

Àkọlé fídíò, Black women live matters: Ọdún 2015 ní àwọn ọlọ́pàá pa India Kager láìní ìdí- Gina Best

Gbogbo wọn ni wọn si ti ko lọ si ibudo iyasọtọ titi ti esi ayẹwo wọn yoo fi jade

Eeyan marundinlaadọrun lajọ NCDC kede pẹlu arun naa ni ipinlẹ Kwara lọjọ Abamẹta