Ọlọ́pàá tó bá ìyàwó Atiku gbé báàgì lóde kan ìjàngbọ̀n

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá yóò fìyà jẹ ọlọ́pàá obìnrin tó bá aya Atiku gbé báàgì lóde

Ọlọpaa to ba aya Atiku gbe baagi lode

Oríṣun àwòrán, @Fifi_Ify

 Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olumuyiwa Adejobi ti sọ pe ọlọpaa obinrin ti wọn yan ti iyawo Atiku Abubakar, iyẹn Titi Abubakar, yoo jiya to tọ gẹgẹ bii ofin ileeṣẹ naa lẹyin ti aworan rẹ gbode nibi to ti gbe baagi iyawo oloṣelu naa dani.

Ọdọbinrin kan, Ifeoma, lo fi aworan naa lede loju opo Twitter rẹ, nibi to ti bu ẹnu atẹ lu ọlọpaa ọhun, to tun tahun si ileeṣẹ ọlọpaa lapapọ.

Ifeoma sọ loju opo Twitter rẹ pe “Ti araalu lasan ba le sọ ọlọpaa di ọmọ ọdọ to n gbe baagi rẹ, nigba wo ni ọlọpaa ko ni gbagbe ojuṣe rẹ ti yoo si maa ṣe ohun ti awọn alagbara ilu n fẹ?”

Ọlọpaa to gbe baagi aya Atiku lọwọ

Oríṣun àwòrán, @Fifi_Ify

Inu akọle ọhun le ti ke si agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa Eko, Benjami Hundeyin pe ko da si ọrọ naa.

Amọ ki Hundeyin to sọrọ ni agbenusọ ileeṣẹ naa l’Abuja, Muyiwa Adejobi ti dahun pe ohun ti ọlọpaa naa ṣe ko ṣe itẹwọgba.

Adejobi ni “Nnkan yii ko ṣe itẹwọgba rara.”

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

“A oo ṣawari ọlọpaa yii, a o si kan si ẹni ti a yan an ti lati maa ṣṣo.”

“A ti kan si ẹka to n ri si akansẹ iṣẹ nileeṣẹ ọlọpaa lati ba wa ṣawari ọlọpaa obinrin naa lati wa sọ tẹnu rẹ, diẹdiẹ ni a oo fọ ileeṣẹ ọlọpaa mọ.”

Kii ṣe igba akọkọ ree ti wọn yoo ṣi ọlọpaa lo ni Naijiria

Kii ṣe igba akọkọ ree ti awọn oloṣelu tabi awọn alagbara ilu yoo lo ọlọpaa ti wọn ni ko maa ṣọ wọ ni ilokulo.

Ti ẹ ko ba gba gbagbe, ẹnu ọjọ mẹta yii ni ọjọgbọn Zainab Duke-Abiola, to jẹ opo oloogbe MKO Abiola ati ọmọ ọdọ rẹ kan wọ gau nilu Abuja lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn lu ọlọpaa obinrin kan niluu bara.

Ọlọpaa naa, Teju Moses ni wọn na titi ti ẹjẹ fi n jade lara rẹ to si n bẹbẹ pe ki wọn gbe oun lọ sile iwosan ki oun ma ba ku.

Lẹyin iṣẹlẹ naa ni Zanab Abiola ati ọmọ ọdọ rẹ naa ti wọn fẹsun kan foju bale ẹjọ.