Èèyàn mẹ́ta, ọkọ̀ méjìlá àti ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ́bù jóná tán bí táńkà epo ṣe gbiná ní Sango-Ota

Awọn dukia to jona

Eeyan mẹta ti padanu ẹmi wọn, nigba ti ọkọ mejila jona guru-guru lasiko ti ọkọ agbepo tanka kan ṣubu lulẹ lagbegbe Toll Gate to wa ni Sango-Ota, ni opopona ilu Eko si Abeokuta.

Eeyan mẹta mii tun farapa ninu iṣẹlẹ naa to waye ni afẹmọju Ọjọbọ.

Akọroyin BBC Yoruba to lọ sibi ti iṣẹlẹ naa, jabọ pe yatọ si awọn ọkọ to jona, ina naa tun kan awọn ṣọọbu kan lagbegbe ọhun.

Sango-Ota

Aago meji oru mọjumọ Ọjọbọ ni tanka epo to gbina ti subu - FRSC

Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si irinna aabo loju popo, FRSC, Florence Okpe fi ṣọwọ si awọn akọroyin, o ni nnkan bii aago kan oru ni ọkọ naa ṣubu, ti ina si sọ lara rẹ.

O ni “Nnkan bii aago kan oru ni ọkọ agbepo kan, ti epo wa niu rẹ ṣubu loju ọna marosẹ Abeokuta si Eko, ti epo to wa ninu rẹ si danu, eyii to mu ko gbina.”

Sango-Ota

“Ni kete ti iṣẹlẹ ọhun waye ni wọn ke si awọn oṣiṣẹ panapana, ti awọn naa si lọ sibẹ.”

“Nigba ti yoo fi di aago mẹrin kọja iṣẹju marun un idaji, ọkọ mejila lo ti jona guruguru.”

"Eeyan mẹta to fara pa nibi isẹlẹ naa ti wa nile iwosan"

Atẹjade naa sọ pe ọkọ akero nla mẹta, kẹkẹ Maruwa mẹrin, alupupu mẹta, bọọsi akero danfo kan ati tanka epo kan lo ba iṣẹlẹ ọhun lọ.

O ṣalaye siwaju si pe eeyan mẹta lo farapa nibi iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti wa nile iwosan ijọba to wa niluu Ota bayii, nibi ti wọn ti n gba itọju.

Awọn to farapa naa jẹ ọkunrin meji ati obinrin kan.

Amọ oku eeyan mẹta ti wọn ti jona kọja mimọ ni wọn ti gbe kuro nibẹ.