Kano: Ìlú àwọn ‘òmùgò’ gba orúkọ tuntun lẹ́yìn àádọ́rin ọdún

Agbegbe Karaye ni ipinlẹ Kano ni ilu awọn omugọ yii wa
Idunnu ati ayọ lo ba de fun awọn ara ilu Unguwar Wawaye, ti orukọ wọn tumọ si ilu awọn omugọ lẹyin ti wọn pa orukọ ilu naa da, lẹyin aadọrin ọdun.
Ilu Unguwar Wawaye jẹ agbegbe to wa ni ijọba ibilẹ Rogo ni ilu Kano to wa ni Ariwa orilẹ-ede Naijiria ni o ti gba orukọ tuntun yii.
Wawaye ni Ede Hausa ti awọn eniyan yii n sọ tumọ si pe omugọ ni wọn, awọn olugbe agbegbe naa ti wọn ba BBC sọrọ ni wi pe awọn eniyan maa n fi orukọ ilu naa bu awọn nigbakigba ti awọn ba jade.
Inu ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa, Bala Sani dun gidigidi lẹyin ti Emir ilu Karaye- ọkan lara awọn Emir tuntun ti Gomina ipinlẹ Kano yan, yi orukọ ilu naa pada si Yalwar Kadana, to tumọ si agbegbe ohun to pọ.
Sani ni ọpọlọpọ igba, loun kii le pe orukọ ilu oun ni ita gbangba nitori itiju naa pọju.
Amọ bayii, o ni inu oun dun gidigidi fun ayipada to de ba orukọ ilu oun.
Isa Yunusa ti oun naa jẹ olugbe ilu yii fi idunnu rẹ han si orukọ tuntun naa.
O ni bayii oun a le tẹsiwaju pẹlu eto igbeyawo oun to wa loju ọna.

Oríṣun àwòrán, Karaye Emirate
Adari ilu na, Mallam Abdullahi Tsoho sọ fun BBC pe awọn gba orukọ naa ni aadọrin ọdun sẹyin nitori orukọ odo to la ilu naa kọja.
Tsoho ni awọn eniyan maa n pe omi naa ni Wawar rafi to tumọ si omi omugọ, lẹyin igba diẹ ni awọn eniyan bẹrẹ si ni pe ilu naa ni ilu awọn omugọ titi ti o fi di baraku.
Gbogbo ilu to wa ni agbegbe naa lo jade lati wa bawọn dunnu lori bi wọn se gba orukọ tuntun lẹyin ọpọlọpọ ọdun.
Asoju Emir Ibrahim Abubakar sọ wi pe Emir naa gbe igbesẹ naa lati le tẹ awọn eniyan ara ilu naa lorun, ati wi pe o seesẹ ki orukọ omugọ naa ma a da wọn laamu.















