Lai Mohammed: Kò sí ohun tó burú nínú kí ìjọba yá owọ láti fi ṣe àwọn ohun amáyédẹrùn

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita fun eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed ti sọ pe, ko si ohun to buru ninu ki ijọba ya owo lati fi ṣe awọn ohun amayedẹrun saarin ilu.
Lai Muhammed lo sọ ọrọ naa nigba to n ṣayẹwo ibi iṣẹ de duro loju ọna oju irin Ibadan si ilu Eko.
O ni "A ko yá owo lati na a lori awọn nnkan miran, ṣugbọn awọn owo ti a n ya, awọn nnkan amayedẹrun bii ọna oju irin, opopona to ja gaara, afara igbalode, ina mọnamọna, atawọn nnkan miran ni a fi n ṣe."
- Ibùdó ìyàsọ́tọ̀ ni mo wà, ló fi pẹ́ kí ń tó sọ̀rọ̀ lórí tírélà tó já l‘Eko - Omotola Jalade Ekeinde
- Ìdẹra dé fún Nàíjíríà! Sani Abacha tún gbé owó míì dé láti Ireland
- Ire ṣ'ọjọ́-ìbí, Mide àti ọkọ rẹ̀ lẹ̀pọ̀, Iyabo Ojo f'aṣọ ilẹ̀ Afirika dárà
- Èèkàn ẹgbẹ́ òṣèlú APC mií Lanre Razak jáde láyé lẹ́yìn àìsàn ráńpẹ́
Lai tẹsiwaju pe "Ko si ohun to buru ninu ki a ya owo, niwọn igba to ba jẹ pe awọn ohun amayedẹrun la fẹ fi owo ọhun ṣe, paapaa to ba jẹ eyii ti yoo pese iṣẹ fun awọn eeyan, ti yoo gbe ọrọ aje wa soke."
Minisita ọhun fi kun un pe inu oun dun si iṣẹ to n lọ lọwọ loju ọna oju irin ọhun.
O ni inu awọn ọkọ oju irin naa mọ lolo, o dun wo loju, o si ba igba mu gẹgẹ ni iru rẹ to wa lawọn orilẹ-ede miran to ti goke agba kaakiri agbaye.
Lai pari ọrọ rẹ pe minisita eto irina mu ori oun wu pẹlu aayan to fi n ṣe iṣẹ opopona oju irin naa.
Hate Speech: Ìjọba àpapọ̀ ṣàlàyé ìdí tó fi ṣàfikún owó ìtanràn ọ̀rọ̀ kòbákùngbé

Oríṣun àwòrán, @thebridgenewsng
Minisita eto iroyin ati aṣa, Lai Mohammed ti ṣalaye idi ti ijọba apapọ ṣe ṣafikun iye owo itanran fun awọn to ba sọrọ odi si ijọba lati ẹgbẹrun lọna ẹẹdeẹgbẹta naira si miliọnu marun un naira.
O ni idi naa jẹ lati kapa awọn kọlọrọsi ti yoo lo ọrọ ikorira lati da orilẹ-ede Naijiria ru.
Lai ṣalaye pe "Idi pataki ti a fi ṣafikun iye owo naa ni pe, awọn eeyan n ru ofin ọhun nigba ti iye owo itanran rẹ wa ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdeẹgbẹta naira nitori o rọrun fun wọn lati san."
- Irú àìsàn wo ló ń ṣe Aisha Buhari tó fi fò lọ sí Dubai fún ìtọ́jú?
- Èèyàn mẹ́tàdínláàdọ́fà ló móríbọ́ lọ́wọ́ Covid-19, 443 míì tún lùgbàdì rẹ̀ lọ́jọ́ Ẹtì
- Èèyàn 16 kú lẹ́yìn tí bàálù Air India já lulẹ̀ , tó sì kán sí méjì ní Kerala
- Ilé ẹjọ́ ti dájọ́ Naira Marley, wọ́n ní kó san owó ìtànràn, kó tún tọrọ àforíjì
O ni awọn ileeṣẹ igbohunsafẹfẹ kan yoo mọọmọ gbe ọrọ kobakungbe sita lori afẹfẹ, ti wọn yoo si gba lati san owo itaran ọhun.
Ọdun 2019 ni ọgbẹni Lai kọkọ kede pe aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu afikun owo itanran ọhun eyii ti wọn fi sinu akọsilẹ iwe ofin to rọ mọ igbohunsafẹfẹ.
O ni ki awọn awọn to n bu ẹnu atẹ lu ijọba lori afikun owo itanran naa mọ pe ọrọ kobakungbe ti da rogbodiyan silẹ lawọn orilẹ-ede kan.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹgbẹrun lọna ẹgbẹrin eeyan lo ku ni Rwanda latari ọrọ ikorira.
Bẹẹ lo tun sọ nipa orilẹ-ede Chad to dẹwọ bi awọn eeyan ṣe n lo ori ayelujara rẹ lati kapa ọrọ ikorira.
Lai pari ọrọ rẹ pe afojusun ijọba ni lati ṣakoso bi awọn eeyan ṣe n lo ori ayelujara lai tẹ oju ẹtọ wọn lati sọrọ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria mọlẹ.
Wo ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa òfin tuntun tó de ọ̀rọ̀ kòbákùngbé

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Laipẹ yii ni ijọba orilẹede Naijiria ti ni ẹnikẹni ti ọwọ ba tẹ pe oun sọrọ kubakugbe yoo san owo itanran miliọnu marun Naira.
Minisita fun eto iroyin ni Naijiria, Alhaji Lai Mohammed lo sọ eleyii ni ilu Abuja lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ atunṣe fun ofin to rọ mọ iroyin ni Naijiria.
Lai Mohammed ni oun gbe igbesẹ naa lẹyin ti oun gba aṣẹ lọwọ Aarẹ Muhammadu Buhari to paṣẹ atunṣe naa lẹyin gbogbo ọrọ kubakugbe to waye ni Naijiria saaju idibo gbogboogbo ti ọdun 2019.
Lati atẹyinwa ni awọn to di ipo mu ni Naijiria to fi mọ iyawo aarẹ Buhari, Aisha Buhari ni wọn ti ṣe ikilọ lori sisọrọ kubakugbe lorilẹede Naijiria.
Kini itumọ sisọrọ kubakugbe?
Sisọrọ kubakugbe niiṣe pẹlu sisọ ọrọ tabi lilo aworan ti o le ṣe ipalara tabi tabuku ba ẹni ti wọn n sọ ọ si lawujọ.
Sisọrọ kubakugbe tun tumọ si piparọ mọ eniyan ati iroyin ẹlẹjẹ nipa ẹnikan lọna ati fi ṣe ẹlẹya lawujọ.
Kini ofin tuntun ti ijọba ṣẹṣẹ fikun sisọrọ kubakugbe lawujọ
Minisita fun eto iroyin ni Naijiria, Lai Muhammed ni ofin tuntun naa ti wọn pe ni 'Edition of the Broadcasting Code' ti mu ayipada pa iroyin to niiṣe pẹlu oṣelu, iroyin abẹle, iroyin yajoyajo ati iroyin karakata ni Naijiria.
Ofin tuntun naa ṣe afikun iye owo ti awọn ẹni ti wọn ba mu pe oun sọrọ kubakugbe yoo ma a san lati N500,000 si N5m.
Ofin to de lilo ẹrọ ayelujara ni Naijiria fun ijọba Naijiria laaye lati ṣe ọfintoto awọn iroyin ti ileeṣẹ iroyin lati oke okun ba n gbe jade ni Naijiria, lati ri wi pe wọn ko gbe iroyin to le e da wahala silẹ ni Naijiria.
Ofin tuntun naa ni ijọba laṣẹ lati sọ igba ti awọn ileeṣẹ iroyin yoo gbe iroyin jade ti rogbodiyan ba bẹ silẹ ni Naijiria.
Amọ, awọn onimọ nipa eto iroyin ati awọn to n lo ẹrọ ayelujara ti fi ero wọn han lori ofin tuntun ti ijọba gbe kalẹ naa.
Alaga tẹlẹri fun ileeṣẹ to n sakoso eto iroyin ni Naijiria (National Broadcasting Corporation), Tony Iredia ti bu ẹnu atẹ lu ofin tuntun naa, to si sọ wi pe o tako ofin to de eto iroyin ni Naijiria.
Ninu ọrọ tirẹ, arakunrin Justin lori ẹrọ Twitter sọ wi pe ohun ko ri iṣoro pẹlu ofin tuntun naa, amọ ijọba gbọdọ le fa ala laarin ọrọ kubakugbe ati eto lati sọ ọrọ lawujọ.
Amọ, minisita fun eto iroyin naa ni ijọba ko ni naani gbogbo ọrọ ti awọn to ba tako ofin naa ba sọ, ati wi pe awon gbe ofin tuntun naa kalẹ fun idagbasoke Naijiria, eleyii o mu ki ijọba laṣẹ labẹ ofin lati ṣe atunṣe ofin to rọmọ iroyin lorilẹede Naijiria loore-koore.
Hate Speech bill: Ilé aṣòfin ṣe tán láti ṣàtúnṣe lórí ìjìyà ikú nínú àbá ọ̀rọ̀ ìkórìra
Sẹnẹtọ to ṣagbatẹru aba to maa ṣe amujuto ọrọ ikorira eyi to wa niwaju ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja, Sabi Abdullahi, sọ pe ile ṣetan lati yọ aba ijiya iku kuro ninu aba ti wọn gbe kalẹ ọhun.
Sẹnẹtọ Abdullahi ni ile yoo ṣiṣẹ lori aba naa lati rii wi pe o jọ ohun tawọn ọmọ Naijiria n fẹ gan an.
Abdullahi sọ pe ọrọ ti awọn to tako aba naa atawọn to fara mọ ọ sọ yoo wulo lati ṣe ofin gidi ti yoo dẹkun ọrọ ikorira lorilẹede Naijiria.
Abala kẹrin aba naa lo sọ pe ẹnikẹni to ba jẹbi ẹsun ikorira yoo lọ sẹwọn gbere, bakan naa iru ẹni bẹẹ tun le gba idajọ iku ti ọrọ ikorira to ba sọ ṣokunfa iku ẹlomiran.
Awọn ajafẹtọ ati ọpọ eeyan ni wọn ti tako aba ọhun, wọn ni ọna lati maa dunkoko mọ awọn eeyan ni, eleyi to lodi si ẹtọ lati maa sọrọ tawọn ọmọ Naijiria ni.
Ṣugbọn Sẹnẹtọ Abudulahi ni ọrọ ikorira ti ṣokunfa iku fun ọpọ eeyan, o ni ohun lo n fa irẹwẹsi ọkan fun ọpọ to si tun ti mu ọpọ gbẹmi ara wọn.
Sẹnẹtọ Abudulahi ṣalaye pe gẹgẹ bi akọsilẹ ajọ iṣọkan agbaye, orilẹede Naijiria ni awọn eeyan to ni irẹwẹsi ọkan ti pọ ju lọ nilẹ Afirika, bakan naa ni akọsilẹ ọhun to fihan pe Naijiria ni iṣẹlẹ ipara ẹni ti pọju ṣikarun un lagbaye.
O ṣalaye siwaju sii pe ohun ti aba yii wa fun naa ni lati dena ifẹmi ṣofo awọn Naijiria lori ọrọ ikorira tawọn kan sọ eleyii to da rogbodiyan silẹ.


















