Internet Fraud: Iléẹjọ́ ní kí ''Yahoo boy'' lọ darí ọkọ̀ f'óṣù mẹ́ta lẹ́yìn tó tan obìnrin òyìnbó jẹ

Oríṣun àwòrán, Facebook/EFCC
Ileẹjọ giga kan niluu Ilorin nipinlẹ Kwara ti dajọ wi pe ki ọkunrin kan, ọmọ ọdun mẹtalelogun lọ dari igboke-gbodo ọkọ fun oṣu mẹta, lẹyin to jẹ ẹsun ilujibi ori ayelujara.
Adajọ Sikiru Oyinloye tun paṣẹ fun Kolade Emmanuel Balogun pe ki o san ẹgbẹrun un lọna aadọta naira gẹgẹ bi owo itanran lẹyin to jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan an.
Lati ọjọ kẹtadinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2020 yii ni ileẹjọ so pe ki Balogun bẹrẹ si ni dari igboke-gbodo ọkọ lẹyin ileeṣẹ ijọba to n ri kikọ ile si ilu.
- Ọ̀rọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ ní Nàìjíríà yìí tí ń kọ àwa Oṣo àti Àjẹ́ lóminú, a fẹ́ wa ǹkan ṣe síi
- Ìpànìyàn tún wáyé ní Akinyele, àwọn ará àdúgbò ṣe ìwọ́de
- Mọ̀ síi nípa Shina Rambo tó pàdé Jesu lọ́gbà ẹ̀wọn lẹ́yìn tó ti jalè
- Mi ò tí ì mọ obìnrin rí; kódà, mí ò ní 'Girlfriend'- Mr Macaroni
- Kọ́ńdọ̀mù tó bẹ́ gbé iléèṣẹ́ ìjọba àti aládáni kan dé ilé ẹjọ́
L'Ọjọbọ, ọjọ kẹtala, oṣu kẹjọ ni EFCC fi ẹsun onikoko kan ọmọkunrin naa pe purọ pe ara rẹ ni Ọgbẹni William Davis ti inagijẹ rẹ n jẹ Behemooth lati tan obinrin alawọfunfun kan jẹ lori ẹrọ ayelujara.
Agbẹjọro fun ajọ EFCC, Aliyu Adebayo ileẹjọ lati fiya to tọ jẹ Balogun nitori ohun to ṣe tako ofin orilẹede Naijiria.
- Wo ọ̀nà márùn ún tí o lè gbà dáàbò bò ara rẹ lọ́wọ́ ìjàmbá láì gbé ìbọn!
- Ilé ẹjọ́ ju ọmọ ìjọ tó fi ìpá bá ọmọ pásítọ̀ rẹ̀ sùn ní ìpínlẹ̀ Ondo sí ẹ̀wọ̀n gbére
- Àwọn ẹgbẹ́ Tijjaniyya ti yọwọ́ kílàńkó Yahaya Sharif kúrò láwo ẹgbẹ́ wọn ní Kano
- "Mi ò ní wọ Uber mọ́ tí wọ́n bá leè fi owó lée nítorí àfikún owó orí tí Sanwo Olu ṣe"
- 'Àwa ọmọ Nàìjíríà tó farapa fẹ́ wálé láti Lebanon, ìjọba kó wa pamọ́'
Amọ agbẹjọro ọmọkunrin naa, Rotimi Oyagbola rawọ ẹbọ si ileẹjọ lati fi oju aanu wo ọdọkunrin naa nirori igba akọkọ ree ti yoo ṣe iru nnkan bẹẹ.
Ṣugbọn, Adajọ ni ko si awawi kan fun Balogun nitori ẹri to daju wa wi pe o jẹbi ẹsun ti wọn fi ka an.
Adajọ Oyinloye tun paṣẹ pe ki wọn gba ẹrọ ibanisọrọ ati ẹrọ kọmputa ti ọmọkunrin naa n lo lati lu awọn eeyan ni jibiti lori ayelujara, ki wọn si ko fun ijọba apapọ.














