Al-Qaeda, ISIS: Amẹ́ríkà ké gbàjarè pé ẹgbẹ́ agbésùmọ̀mí n palẹ̀mọ́ láti wọ Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, YouTube/Boko Haram
Orileede Amẹrika ti figbe ta pe ikọ ẹgbẹ agbesunmọmi Al-Qaeda n gbero lati kogun ja iwọ ila oorun Ariwa Naijiria.
Bẹẹ naa ni wọn sọ pe Al-Qaeda n lo anfaani pe awọn ilẹ Afrika ko ribi koju ipenija Covid-19 lati pẹka de awọn aaye wọn mi.
Ikilọ yi waye lasiko ti Dagvin Anderson, ọgagun ikọ ọmọ ogun Amẹrika ni ilẹ Afrika n ba awọn akọroyin sọrọ loju opo ibanisọrọ Zoom lọjọru.
O ni Al Qaeda n gbe igbesẹ lati pẹka sii paapa julọ sawọn agbegbe mii ni ila oorun ilẹ Afrika.
O ṣalaye pe awọn ti n jiroro pẹlu ijọba Naijiria lori ọrọ yi.
''A ti ba ijọba Naijiria fọrọjomi toro ọrọ ti a ṣi n ṣe bẹẹ nipa ṣise alabapin iroyin to tẹwa lọwọ ati mimọ ohun tawọn alaburu yi n ṣe''

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O sọ pe ṣiṣe alabapin iroyin laarin Amẹrika ati Naijiria ṣe pataki lati le fi mọ ohun ti Boko Haram ati ISIS n ṣe lati le fi koju wọn.
O ni o ṣeni laanu pe gbogbo bi awọn ṣe n gbiyanju lati koju awọn agbesunmọmi yi, niṣe ni wọn gbooro sii.
O ni nkan meji lo wa nidi iṣẹlẹ yi.
''Akọkọ ni pe ijọba ti ọrọ kan gaan ni lati gbajumọ kikoju awọn agbesunmọmi yi kawọn to ba fẹ gbaruku tiwọn le ri wi pe wọn mura sii. Ẹlẹẹkeji ni pe ki awọn ti wọn n pawọpọ ba wọn ja naa ma ṣe foju di awọn agbesunmọmi yi''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ikú wo ló pa ọmọ ogun Nàìjíríà mẹ́wàá àti ọ̀kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìyàwó?
- Ìjọba Oyo fẹ́ mọ ikú tó pa akẹ́kọ̀ọ́ UI níléeṣẹ́ tó ń ṣe ọṣẹ
- Àwòkọ́ṣe ìwà ìrẹ̀lẹ̀, òtítọ́ àti olùfẹ́ mẹ̀kúnnù ni Ayo Fasanmi - Ìjọba Osun
- Àwa àti fijilanté pẹ̀lú ọdẹ́ ìbílẹ̀ ló dojú kọ adigunjalè ní First Bank Okeho - Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá
- "Ọmọ mi kò tíì mọ̀ pé òun ti di ìlúmọ̀ọ́ká, ó ń wádìí bó ṣe ń rí ara rẹ̀ lórí ayélujára"
- Ìtàn ọba Yorùbá tí wọn yẹgi fún torí ó jí ọmọ gbé ṣe ètùtù
- Ẹ káàbọ̀ sọ́jọ́ Arafat, tí Ọlọ́run yóò fi ààwẹ̀ Mùsùlùmí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́
Boko Haram da ìbọn bo ọkọ̀ gómìnà Borno, ẹ̀ṣọ́ àláàbò rẹ̀ farapa

Oríṣun àwòrán, Facebook/Gov Zullum
Ijọba ipinlẹ Borno ti fi idi rẹ mulẹ pe, lootọ l'awọn agbebọn Boko Haram kọlu awọn ọkọ to n kọwọrin pẹlu gomina ipinlẹ naa, Babagana Zullum ni Ọjọru.
Agbẹnusọ fun gomina naa, Mallam Isa Gusau ṣalaye pe, ori ko gomina Zullum yọ lai farapa ṣugbọn diẹ lara awọn to baa rin, to fi kan awọn ẹṣọ alaabo, fara ṣeṣe.
Isa fi kun un pe, ilu Baga ni gomina naa n lọ nigba ti ikọlu naa waye.
Bawo lo ṣe ṣẹlẹ?
Ni Ọjọru ni iṣẹlẹ yii waye ni nnkan bii agogo mẹrin irọlẹ lasiko ti gomina naa fẹ wọ ilu Baga l'awọn agbọn naa ba ṣina ibọn bolẹ.
Awọn ẹṣọ alaabo to wa pẹlu rẹ naa daa ina ibọn bolẹ.
Ṣaaju asiko yii lawọn ologun ti n sọ fun gomina naa pe awọn ti gba ilu Baga pada lọwọ awọn Boko haram ati pe awọn ti gba akoso ibẹ.
Gomina gba ibẹ pada si ilu Monguno lẹyin iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Twitter/HQNigerianArmy
Inu igbo ni pupo awọn to ba gomina ipinlẹ Borno naa rin ,fi aya wọ pamọ si
Awọn ikọ agbebọn Boko Haram n ṣe ọpọlọpọ ọṣẹ lagbegbe ila oorun ariwa orilẹede Naijiria, iroyin to si n jade ni pe ọpọ emi ati dukia ni wọn fi ṣofo nibẹ.
Laipẹ yii ni wọn pa awọn oṣiṣẹ aṣeranwọ mẹrin ni ipinlẹ naa. Nigba naa, gomina Zullum ṣe apejuwe awọn oṣiṣẹ naa gẹgẹ bi akinkanju
Iye awon igba ti wọn ti kọlu Borno laarin ọdun sẹyin.

Oríṣun àwòrán, YouTube/Boko Haram
Eyi ko ni igba akọkọ tawon agbebon yii yoo maa kọlu ipinlẹ Borno.
Lẹyin ti Aare Buhari wọle saa keji pẹlu ileri ati ṣẹgun wọn ikọlu awọn ẹgbẹ agbesunmọmi yii ko dẹkun.
Eeyan mẹtadinlogun ni wọn pa loṣu karun ọdun 2020, ti mẹtalelogun miran si tun ku lọwọ awọn agbebọn ni ileto Gajihana, ni ijọba ibilẹ Magumeri.
Ko din ni ọgbọn ero ọkọ kan tun pa lagbegbe Auno nitosi Maiduguri loṣu keji ọdun 2020.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn agbesunmọmi Boko Haram tẹlẹ gba idande
Ileesẹ Ologun ilẹ wa ti da awọn ọmọogun Boko Haram toto okoolerugba ati mẹrin silẹ lahamọ pẹlu afikun pe wọn ti se idanilẹkọ to yẹ fun wọn lati ri daju pe wọn jawọ kuro ninu iwa ipanle, ki wọn to tu wọn silẹ.
Akọroyin ileesẹ BBC, Ishaq Khalid jabọ latilu Abuja pe awọn ọmọ ikọ Boko Haram naa ti lanfaani lati maa rin, maa yan laarin ilu.
Gomina ipinlẹ Borno lo tẹwọgba wọn
Ọgagun to wa fun eto ironupiwada awọn ọmọ ikọ Boko Haram lẹkun ila oorun ariwa orilẹede yi, lo ko awọn ọmọ ikọ Boko Haram naa kalẹ fun gomina ipinlẹ Borno, tii se ọkan lara awọn ipinlẹ ti Ikọ agbesunmọmi naa ti se ọsẹ julọ lati ọdun mẹjọ sẹyin.
Wayi o, idande awọn ọmọ ikọ Boko Haram yi lo se pẹkinpẹki pẹlu fọnran aworan tuntun kan ti ikọ Boko Haram fi lede, to se afihan awọn ọmọbinrin Chibok ti wọn ni awọn ko nife lati pada wale mo.
Ọkan lara awọn obinrin Chibok to sọrọ ninu fọnran naa, wipe awon ko ni pada sọdọ awọn obi awọn, ti wọn si rọ awọn obi wọn lati gba esin Musulumi. Sugbọn, awọn ọmọbinrin ọlọpa ti iko Boko Haram ji gbe, n sunkun kikoro ninu fọnran na.

Oríṣun àwòrán, BORNO STATE GOVERNMENT
Adari ikọ Boko Haram , Abubakar Shekau, ninu fọnran to ti soro lede Hausa, sọ wip,e digbi ni ara ohun wa, ti ko si si ohunkohun to se ohun.
Shekau ni Boko Haram lo ja ọkọ ofurufu ologun ilẹ wa,kii se pe o bajẹ.
Shekau so wipe, ikọ oun lo ja ọkọ orufufu awon ọmogun Naijiria bọ, ati wipe ogun sẹsẹ bẹrẹ pẹlu ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ati agbegbe Lake Chad ni.
Iko Boko Haram ti ran ẹgbẹgbẹrun awọn eniyan lọ si ọrun, lati bi ọdun mewa, ti wọn ti bẹrẹ si n sọse lagbegbe ila oorun ariwa Ile-Naijira, ti wọn si fi tipa ko awọn akẹkọbinrin Chibok lọdun 2014.













