Iṣẹ́ bọ lọ́wọ́ Ọgágun àgbà Niger lórí ìkọlù tó ṣékú pá ọmọ ogún 89

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Iṣẹ ti bọ lọwọ ọgagun agba ileeṣẹ ologun lorile-ede Niger lọjọ mẹrin sigba tawọn agbebọn pa eeyan mọ́kàndínláàdọ́rùn ún ni ẹka ileeṣẹ ọmọ ọlogun kan.
Eyi ni iye eeyan to pọju lọ to ku lọjọ kan ninu akọsilẹ ilẹ naa.
Lori redio ni wọn ti kede iyọninipo ọgagun Ahmed Mohammed ati awọn ọgagun mẹta miran lẹyin ipade igbimọ alaṣẹ.
Laarin ọdun meji ti ọgagun Mohammed ti wa nipo, niṣe ni ikọlu ti n waye lemọ lemọ pẹlu awọn ikọ agbesunmọmi alakatakiti ẹsin Islam to ni ajọṣepọ pẹlu al-Qaeda ati Islamic State (IS).
Ọgagun Salifu Modi ni wọn fi rọpọ rẹ bi wọn ṣe yọọ nipo tan.
Ẹwẹ, orile-ede Niger ti kede idaro ọlọjọmẹta lati fi kẹdun iku awọn ọmọ ogun mọ́kàndínláàdọ́rùn ún to padanu ẹmi wọn ni ilẹeṣẹ ologun Chingedor camp ni iwọ oorun agbgbe Tillaberi.
Loṣu to kọja ọmọ ogun mọkanlelaadọrin ni awọn agbesunmọmi ṣeku pa nileeṣẹ ologun Inates camp lagbegbe kan naa.

Oríṣun àwòrán, Reuters
Lọwọlọwọ bayi, aarẹ ilẹ Niger, Mahamadou Issoufou ati awọn aarẹ agbegbe Sahel wa ni ilẹ Faranse nibi ipade pẹlu aarẹ Macron.
Ni ibẹrẹ ipade naa to n waye ni Pau, aarẹ Macron ati awọn olori orileede wọn yi ṣe ayẹsi fawọn ọmọ ogun to fẹmi wọn lelẹ ni Mali loṣu to kọja.
- Ìjọba Canada kò gbó nípa ìgbéṣẹ̀ Harry àti Meghan láti wá sí ilẹ̀ wọn
- Ọdún mọ́kànlá sẹ́yìn ni K1 ti ń béèrè fún oyè Mayegun lọ́wọ́ mi - Alaafin
- Àwọn sẹ́nétọ̀ Nàìjíríà fa ìbínú yọ 'torí N2Miliọ̀nù owó àjẹmọ́nú Kérésì tí wọ́n fún wọn
- Owó orí VAT di 7.5% láti 5% lẹ́yìn tí ààrẹ Buhari buwọ́lu àbá ètò ìnáwó
Ọgbẹni Macron ti beere pe ki awọn aarẹ wọn yi fi atilẹyin wọn hansi ikọ ọmọ ogun ilẹ Faranse ẹlẹgbẹrun mẹrin ti ọpọ n bẹnu atẹ lu tohun ti bi ipenija aabọ ti ṣe n peleke si.
Awọn olori orile-ede Chad, Mali, Niger, Burkina Faso ati Mauritania wa nibi ipade naa.














