Ìbúgbàmù àdó olóró pa èèyàn kan ni Mubi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ibugbamu ado oloro ti pa ọdọmọde kan ti awọn meji miiran si farapa nilu Mubi, ipinlẹ Adamawa.
Kọmisọna feto iroyin nipinlẹ Adamawa, Ahmad Sajoh fidi iṣẹlẹ naa mulẹ.
Amọṣa, ọgbẹni Sajoh di ẹbi ibugbamu naa le awọn majeṣin kan ti wọn n ṣa ilẹ kiri lawọn ibudo idalẹ si kan nibẹ ati pe kii ṣe awọn agbesumọmi lo ṣọṣẹ.
"Kii ṣe ikọlu awọn agbesumọmi, iṣẹ ọwọ awọn majeṣin to n wa ohun ti wọn yoo jẹ tabi ta ni."
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
O ni awọn agbofinro ti ṣawari ẹbi awọn ọeeyan naa.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn ni ọsan ọjọ aiku nitosi ibudo ikẹgbin dasi kan lopopona Kabang ni ijọba ibilẹ Mubi.
Wọn fi kun un pe ọdọmọde to mu eroja ado oloro naa dani nigba to bu ku lẹsẹkẹsẹ, ṣugbọn wọn ti gbe wọn lọ si ileewosan ijọba ni Mubi.








