Òpópónà Mokwa sí Jebba; Afáárá fún àwọn awakọ̀ wó lulẹ̀

Jebba road

Oríṣun àwòrán, Facebook/Lara Wise

Àkọlé àwòrán, FRSC gba awọn awakọ niyanju lati gba popona Lokoja ti wọn ba n lo si olu ilu Naijiria, Abuja.

Afaara to wa ni oju opopona Mokwa si Jebaa ti wo lulẹ, lẹyin ti ojo arọọrọda sọsẹ lagbeegbe naa.

Agbẹnusọ fun ajọ to n risi ọrọ oju popo, Bisi Kazeem nigba to n ba BBC Yoruba sọrọ fikun un wi pe ki awọn awakọ o sọra lati gba ọna naa.

Ninu ọrọ rẹ, Kazeem ni looto ni isẹlẹ naa waye ni ipinlẹ Niger, lẹyin ti ojo rọ.

Àkọlé fídíò, Ọ̀rọ̀ fún àwọn tó ń lo ike rọ́bà

O gba awọn awakọ niyanju lati gba opopona Lokoja ti wọn ba n lo si olu ilu Naijiria, Abuja.

Iroyin fi lede wi pe ọna Mokwa si Jebba ni ọpọlọpọ eniyan ma n gba lọ si Ilorin ati si Abuja.