Olórí North Korea ti balẹ̀ fun Ìpàdé pẹlú Ààrẹ Trump

Kim Jong-un bo se n gunle ni papako ofurufu

Oríṣun àwòrán, Singapore/MOCI

Àkọlé àwòrán, Kim gunle fun ìpàdé pẹlú Donald Trump

Olórí orílèèdè North Korea Kim Jong-un tí tẹ̀dó sí orílèèdè Singapore fún ìpàdé rẹ̀ pelu Ààrẹ Donald Trump Amẹrika.

Ìpàdé manigbagbe ọ̀hún láàrin àwọn olórí méjèjì yóò wáyé ní ibi ìnajú Sentosa lójó ìṣẹgun.

Èyí ni ìgbà àkọkọ tí olórí North Korea kánkan yóò ṣe ìpàdé pẹlú olórí Amẹrika.

Ṣáájú ko to gbérà fún ìpàdé náà, Trump ṣe àpèjúwe ìpàdé yìí gẹgẹ bí anfààní ati mú alafia wà tó sì ni kò sí ẹni tó mọ òun t'àwọn yóò bá pàdé ni ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà.

Vivian Balakrishnan n ki Kim Jong-un kaabo

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán, Minista ton risi oro ilẹ okere orileede Singapore Vivian Balakrishnan n ki Kim Jong-un kaabo

Lọ́jọ́ àìkú ni Ààrẹ Trump yóò gúnlẹ̀ fún ìpàdé náà.

Ìrètí Washington ni pé ìpàdé náà yóò ṣe atọna bí Kim yóò ṣe jọwọ àwọn òun ìjà oloro rẹ.

Awọn olori mejeji yóò ṣe ìpàdé pẹlu Olootu ijọba orileede Singapore, Lee Hsien Loong ṣáájú ipade wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: