North Korea da awọn ọmọ ilẹ Amerika mẹta ti wọn wa l'ẹwọn silẹ

Oríṣun àwòrán, Reuters/AFP
Aarẹ Amẹrika Donald Trump ti kede pe orilẹede North Korea ti da awọn ọmọ ilẹ Amerika mẹta ti wọn wa l'ẹwọn silẹ,
Ọpọ eeyan lo ri igbesẹ yii gẹgẹ ohun rere ṣaaju ijiroro ti yoo waye laarin Aarẹ Trump ati Aarẹ orilẹede North Korea, Kim Jong-un.
Aarẹ Amẹrika sọ pe, oun yoo ki wọn kaabọ ti wọn ba de pẹlu akọwe agba orilẹede Amẹrika, Mike Pompeo.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ọgbẹni Pompeo ti wa ni ilu Pyongyang, nibi ti o n ti ṣeto fun ijiroro laarin Aarẹ Amẹrika ati Aarẹ orilẹede North Korea.
Ile Ijọba Amẹrika White House sọ pe, koko lara awọn ọmọ ilẹ Amẹrika naa le, ti wọn si lee rin funra wọn, laisi ẹni to ran wọn lọwọ ninu ọkọ ofurufu.
Ẹwẹ, Aarẹ Trump fi idunnu rẹ han loju opo ikansiraTwitter rẹ, bakan naa lo sọ pe, oun n foju sọna fun ijiroro oun pẹlu Aarẹ North Korea.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Awọn ọmọ ilẹ Amẹrika mẹta naa ni wọn ran lọ s'ẹwọn lori ẹsun wipe, wọn kopa ninu ohun to tako ofin orilẹede naa.








