Itele Yekini Bakare- Lord Lucifer jẹ́ fíìmù kan tó yàtọ̀ ní gbogbo ọ̀nà

Oríṣun àwòrán, @Itele
Nínú ìfọ̀rọ̀wérọ ti o wáye lónìí pẹ̀lú gbajúgbaja òṣèré Nollywood, Ibrahim Yekini Bakare ti gbogbo ènìyàn mọ si Itele D Icon sàlàyé pé, fíìmù ti òun fi ọwọ́ ara òun ṣe ní òun fi di gbájúgbàja.
Yekini sàlayé pe ọ̀pọ̀ ìgbà ni òun ma hu ìwà líle nínú èré tiata àti ṣiṣe janduku nínú fíímu lati jẹ́ ọ̀nà láti di ilú mọọka.
O ní ọ̀na láti jẹ ki àwọn ènìyàn mọ pé ọmọ kan wà ti o n ṣe ǹkan bayiìí, sùgbọ́n lẹ́yìn ti ọwọ́ tè eeku ida tán ni àwọn ṣẹ̀ṣẹ̀ wá fi han àwọn ènìyàn pé ìmọ̀ ko tán sibi kan.
Yekini Bakare ni òun ko ni ànfani láti lọ si ilé iwé gíga nítori pé Ọlọrun ko fi bẹ́ẹ̀ ṣẹgi olà fun àwọn òbi rẹ̀ nítori náà ni òun fi di èrò Eko níbi ti ó ti ri oore-ọ̀fẹ́ láti darapọ mọ eré tíatà.
Itele fi kún un pé nkan ìwúri ti o kọ́kọ dùn mọ òun jùlọ ni pé nínú fíìmù àgbéléwò Yoruba àti èdè yìnbo, fiimu òun ni àkọkọ to já ìwọ̀n gbendeke mílíọnu méji to wo fọ́nran lóri YouTube.
Itẹlẹ ni eyi jẹ ohun ayọ eyi ti ko ti sí ẹni to bi irú ànfani bẹ́ẹ̀.

Oríṣun àwòrán, @Itele
Lóri bí ọ̀pọ̀ àwọn elére tíàta ti wọn maa n fi amúlùmála èdè òyìnbo nínú fiimu Yoruba, Yekini gbà pé kò dára to.
- Ìjọba Ondo, inú fìfo la fi ń ṣiṣẹ́, ẹ ṣan ọ̀pọ̀ owó oṣù tẹ jẹ wa - Àwọn dókítà fárígá
- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi àwọn afurasí tó pa àkẹ́kọ̀ọ́ LASU sí ẹ̀wọ̀n
- Obìnrin Kwara tí wọ́n tà sóko ẹrú ní Lebanon figbe ta, ọwọ́ tẹ èèbó kọ̀ráà tó ṣiṣẹ́ náà
- Ǹjẹ́ ọmọ Buhari lásẹ láti wọ Ọkọ̀ òfúrufú Nigeria Air force lọ sí òde?
Itẹlẹ ni olúkuluku ni ìdí ti wọ́n fi n ṣe ǹkan ti wọ́n ṣe, ó fi kún un pé àwọn oga ninu eré tíàta náà ti ń ba àwọn òṣèré sọọ pé, bi wọn ba fẹ jẹ́ ọsákála ki wọ́n jẹ́ ọ̀ṣákalá.
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
Nipa àwọn ti wọ́n ariwo pé ìbálopọ nínú tíàta Yoruba pọ, sùgbọ́n Bakare ni nítori pé ẹni à n wò ni iṣẹ́ awọn, sùgbọ́n ǹkan to wọ́pọ̀ ni ninu gbogbo iṣẹ́ lágbàyé.
O fi kùn pé ọ̀pọ̀ ni kò mọ ǹkan to n se, sùgbọ́n ẹni tí o ba lógo kò si ọ̀gá ti yóò tori ìbálopọ̀ lé ẹnikẹni lẹ́nu iṣẹ́.
Itẹlẹ ni pe nítori bi o ba ṣe de ni Ọlọrun ti fi Ogo rẹ̀ si lára ti wọ́n a si ṣe ǹkan to ba yẹ.
O rọ gbogbo ọdọ láti ni ìtẹriba, nítori pe aini ìtẹriba maa n ba orirere ènìyàn jẹ́ ni.
















