LASU student killing: Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí wọ́n fi àwọn tó pa àkẹ́kọ̀ọ́ LASU sí ẹ̀wọ̀n

Oríṣun àwòrán, Nigeria Police
Ile ẹjọ ti ni ki wọn o fi awọn ti wọn fi ẹsun kan pe o pa akẹkọbinrin Fasiti ipinlẹ Eko, Favour Oladele.
Awọn afurasi mẹtẹẹta, Philip Segun, Owolabi Adeeko, to jẹ ọrẹkunrin oloogbe, ati iya rẹ, Bola, ni wọn gbe lọ sile ẹjọ magistreti.
Onidajọ Olukunle Idowu, ti ile ẹjọ Majistreti naa gẹgẹ bi iwe iroyin Vanguard ṣe sọ, dajọ pe ki wọn o fi wọn pamọ si ọgba ẹwọn Ileṣa titi di ọjọ kẹẹdọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2020, ti igbẹjọ yoo waye nile ẹjọ giga lori ẹsun ti wọn fi kan wọn.
Favour, ni iroyin sọ pe o kuro nile l'ọjọ kẹjọ, oṣu Kejila, ọdun 2019, to si di awati. Lẹyin naa ni wọn ri oku rẹ, ṣugbọn ti awọn ẹya ara rẹ kan ko si nibẹ mọ.
Iwadii awọn ọlọpaa lo si fihan pe, irinajo arabinrin yii jọ mọ lilọ si ile ijọsin Segun to wa ni ilu Ikoyi-Ile nipinlẹ Osun.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo wọn pẹlu Adeeko lo ti ṣalaye pe, pasitọ fun oun ni ọmọ odo lati fi lu u lori, ki oun pasitọ to o fi ọbẹ yọ ọkan rẹ, eyi to fi se asejẹ fun Adeeko ati iya rẹ.










