Nigeria Police: Èsì àwọn ọmọ Nàìjíríà tó tẹ̀lé bí iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe yin ara rẹ̀

Odiwọn aseyọri rẹ ti ileesẹ ọlọpa gbe jade
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Lori kaadi ti wọn fi sita loju opo ayelujara Twitter wọn, ileesẹ ọlọpaa sọ pe kaadi naa jẹ afihan akojọpọ awọn aṣeyọri wọn laarin ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2019 si ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kinni, ọdun 2020.

Wọn tọka si awọn 'ẹka' bi awọn afurasi, ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun, ti ọwọ tẹ, to fi mọ iye ọkọ ti wọn jigbe, ṣugbọn ti ọlọpaa gba pada, awọn afurasi ajinigbe ati adigunjale, to fi mọ iye nkan ija oloro ti wọn ri gba.

Ṣugbọn ṣa, bi awọn ọmọ Naijiria kan ṣe n gboriyin fun awọn ọlọpaa ni awọn kan n sọ pe awọn ọmọ Naijiria lo yẹ ko fi iru kaadi igbelewọn naa sita, kiiṣe ileeṣẹ ọlọpaa.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Bakan naa ni awọn kan tun n sọ, paapa labẹ ikede ileeṣẹ ọlọpaa ọhun pe, o yẹ ki wọn o kọ iye aṣita ibọn ọlọpaa to pa araalu, riba gbigba, iye awọn ọdọ ti ọlọpaa fiya jẹ lọna aitọ, ati awọn ẹsun miiran ti araalu fi n kan awọn ọlọpaa si ori kaadi naa.

Yatọ si eyi, awọn kan sọ pe o yẹ ki wọn kọ iye afurasi ti ọrọ wọn wa nile ẹjọ, ati awọn to ti gba idajọ sori kaadi igbelewọn naa.

Ọlọpaa Naijiria

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn kan tilẹ sọ pe ko dara bi wọn ṣe gbe kaadi igbelewọn naa, to ṣafihan ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kinni, ọdun 2019 si ọjọ kẹrindinlogun oṣu Kinni, ọdun 2020, jade ni ọjọ kẹsan an, oṣu Kinni, 2020.

Titi di akoko yii, ileeṣẹ ọlọpaa ko tii f'esi si ọkankan ninu awọn esi araalu naa.

Àkọlé fídíò, 'A rí wàhálà táwọn èèyàn ń kojú nilẹ̀ẹ̀ Yorùbá la ṣe fi "Amotekun" fi ọkàn wọn balẹ̀'