Nigeria Police: Ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ lórí ọlọ́pàa'tó lo ‘POS’ fi gba rìbá’

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile iṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijria ti fi lede wi pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori ọlọpaa to n lo ẹrọ igbalode ti wọn n lo lati fi owo ranṣẹ POS fi gba owo lọwọ eniyan.
Eyi ko ṣẹyin bi fidio kan sẹ jade lori ẹrọ ayelujara nibi ti ọlọpaa to wa loju popo ti n paṣẹ fun ẹni ti wọn da duro lati mu ẹrọ ATM ti wọn fi n gba owo rẹ jade lati san owo.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Arakunrin naa ti ọlọpaa fẹ gba owo lọwọ rẹ wa kọjalẹ wi pe oun ko ni fi ATM oun silẹ fun ọlọpaa lati yọ owo pẹlu rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa to ni iwadii naa ti bẹrẹ fi lede ninu atẹjade ti wọn fi lede ni Ọjọbọ.
Ninu atẹjade ọhun, Ọga Agba Ọlọpaa, Mohammed Abubakar Adamu ni awọn korira iwa ibajẹ ni gbogbo ọna, ati pe awọn ṣisẹ lati ri i wi pe iwa ajẹbanu di awati ni ajọ ọlọpaa lorilẹede Naijiria.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Wọn ni iwadii ti bẹrẹ lati mọ boya fidio naa jẹ ootọ, ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ati iye awọn ọlọpaa to kopà ninu iṣẹlẹ ọhun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Bakan naa ni wọn sọ wi pe, ti fidio naa ba jẹ otitọ, awọn yoo ri i wi pe wọn fi iya to tọ jẹ gbogbo ẹni to ba lọwọ ninu iwa ibajẹ naa.
Amọ ajọ ọlọpaa wa rọ awọn eniyan lati ri i wi pe wọn ṣeranwọ fun wọn lati fi oju awọn ẹni ibi lede ati ki wọn fi iroyin lede nipa ẹni ọhun ti wọn mọ nipa iṣẹlẹ naa.














