Bobrisky: Àsìkò tó tí á da omi ata sí ara wa lójú

Oríṣun àwòrán, @Bobrisky
Lánà òde yìí ni òkìkí kàn pé ọgá àgbà ilé iṣẹ̀ ọna àti àṣà Olusegun Rusewe yóò lọ fi ẹ̀wọ̀n jura nítori ìwà ọ̀yáju to hù si ilé ẹjọ́.
Ẹ̀wẹ̀, èyi jẹ́ ki ọ̀rọ̀ náà gbìnàyá lori ẹ̀rọ ayélujára, nitori ǹkan to ti sẹ̀lẹ̀ ní ǹkan bi oṣù díẹ̀ sẹ́yìn nígbà ti Olusegun Rusewe sọ fún Idris Olarenwaju ti gbogbo èniyàn mọ si Bobrisky pé yóò fi ẹ̀wọ̀n jura.
Lẹ́yin ti ìròyìn náà jáde ni àwọn ènìyàn ti bẹ̀rẹ̀ si ni sọ pé, ènìyàn kò gbọdọ máa gbẹ́ kòtò ọ̀tá jin nítori ìgbà le yí padà.
Bobrisky ti wá fèsì lówùrọ òni lórí àtẹjíṣẹ̀ Instagram rẹ̀ pé: "Ó dàbi pé àsìkò dída ata sírawa lóju nìyìí, àwọn ọ̀tá òun to ni òun ko ni sinmi yóò ma jẹ ẹ̀bà àti ilá láye ṣùgbọ́n itẹ oku ni wọ́n a ti lọ fọ ọwọ́ wọ́n".
Pẹlu eleyii, awọn ololufẹ rẹ n kan sara si i ni.

Oríṣun àwòrán, Bobrisky
Tí ẹ ò bá gbàgbé olùdári ileeṣẹ Arts & Culture nínú iwé ìròyìn Vanguard ti bura pé òun yóò fí ojú rẹ̀ hàn mabo bí o ṣe pèé ni "adoju tini".
O ni "ti Bobrisky bá n ṣe àṣeyori nínú ìwà àgberè tó n fi ṣiṣẹ́ ṣe, báwo ní a ṣe fẹ́ pàrowà si awọn ọdọ Nàìjíríà láti ṣe ǹkan to tọ̀na".
Tí Bobrisky si fun un lésì pé:
" Ẹ jọ́wọ́ ẹ bá mi sọ fún un pé mo ń dúró dè é."
Igbà yẹn ni yóò mọ pé àwọn ọgá rẹ̀ nijọba ni mò ń ba ṣe; kìí ṣe irú àwọn ọjẹ̀ wẹ́wẹ́ bíi tírẹ̀.
Bobrisky ni o fí ǹkan tó ṣe pàtàkì sílẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Nàìjíríà láti maa rojọ́ Bobrisky.














