Bobrisky: Olusegun Runsẹwẹ, o kéré sí nọ́mbà àwọn tí mò ń bá se!

Ọrọ n ba ọrọ bọ laarin awọn mejeeji.
Bobrisky ni Runṣewe n dunkooko mọ oun.
Lẹ́yìn ọrọ tí oludári àgbà fun ile iṣẹ to n ri si ọrọ aṣa ati iṣe lorilẹ-ede Naijiria, National Council for Arts and Culture (NCAC), Otunba Olusegun Runsewe ṣe sí Okuneye Idris Olarewaju ti gbogbo ènìyàn mọ si Bobrisky pé òun yóò fi imú rẹ̀ dárin.
Bobrisky náà ti fèsí sí alákóso Arts & Culture pé ọmọ ọwọ́ ní, àwọn to jẹ́ ọ̀gá ni ìjọba fún ni òun ń ba ṣe.

Nínú èsì rẹ̀ tó fi léde lójú òpo Instagram, Bobrisky ní " mo gbọ́ pé ẹnikan nínú ìjọba sọ̀rọ̀ nípa mí láìpẹ́ yìí.
" Ẹ jọ́wọ́ ẹ bá mi sọ fún un pé mo ń dúró dèé."
ìgbà yẹn ni yóò mọ pé àwọn ọgá rẹ̀ nijọba ni mò ń ba ṣe; kìí ṣe irú àwọn ọjẹ̀ wẹ́wẹ́ bí tí rẹ̀.
O fí ǹkan tó ṣe pàtàkì kálẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Nàìjírríà láti maa rojọ́ Bobrisky.
Tí ẹ ò bá gbàgbé olùdári Arts & Culture nínú iwé ìròyìn Vanguard ti bura pé òun yóò fí ojú rẹ̀ hàn mabo bí o ṣe pèé ni "adoju tini".
"Adójú ti ni àti orílẹ̀-èdè ni Bobrisky".
O bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú títa ìpára tí wọ́n fi n bóra, ní sin yìí ó ti gúnmú, o tún yọdi naa.
Ti Bobrisky bá n ṣe àṣeyori nínú ìwà àgberè tó n fi ṣiṣẹ́ ṣe, báwo ní a ṣe fẹ́ pàrowà si awọn ọdọ Nàìjíríà láti ṣe ǹkan to tọ̀na. Lóòtọ́ ó lẹtò sùgbọ́n kìí ṣé ni àyíká Nàìjíríà.
A ní àwọn èèyàn bi tirẹ, sùgbọ́n wọ́n o gbé Nàìjíríà. Tí a o ba tètè pẹ̀ka ìrókò rẹ̀ nísinyìí ẹbọ ni yoo ma gba.












