US vs Iran: Ilé Asòfin US dìbò láti dín agbára Ààrẹ Trump kù

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ile Igbimọ Asofin lorilẹede Amerika ti fi ontẹ lu u lati din agbara Aarẹ Donald Trump ku lati le jagun pẹlu orilẹede Iran.
Idibo naa ni awọn ile igbimọ asofin di fun pẹlu iye awọn ẹgbẹ oṣelu Democrats si ju ti awọn Republican lọ, pẹlu ibo 224-194.
Amọ o ṣeeṣe ko ni idena ni ile Asofin Agba ni bi ti ẹgbẹ oselu Republic ti pọ ju Democrats lọ.
Awọn asofin naa n dibo wi pe Aarẹ Trump yoo nilo ki ile igbimọ Aṣofin buwọlu igbeṣẹ aarẹ lori orilẹede Amerika.
Amọ orilẹede Iran ati US ko i tii sọ boya ija naa si tẹsiwaju, ti wọn yoo si gbena woju ara wọn.
Ni ọsẹ yii ni orilẹede Iran yin ado oloro si ibudo ikọ ọmọogun ilẹ Amerika to wa ni Iraq, amọ ko si ọmọ ilẹ Amerika naa to ṣeṣe ninu ikọlu naa.
Eleyii ko ṣẹyin bii ilẹ Amerika ṣẹ pa Ọgagun ati adari ikọ ọmọogun ilẹ Iran,Qasem Soleimani ni papakọ ofurufu Baghdad ni orilẹede Iraq.
Nitori naa ni idibo naa ṣe paṣẹ fun Aarẹ Donald Trump lati maṣe lọ ikọ ọmọogun ilẹ Amerika lati koju ija si Iran lai gba aṣẹ ilẹ igbimọ asofin orilẹede naa.












